Haa, ọrọ buruku ti Ọṣọba sọ si Baba Adebanjo ti da wahala silẹ o

Aderounmu Kazeem

Larin awọn agbaagba Yoruba, ati laarin awon ọdọ pẹlu awọn ẹgbẹ loriṣiriṣi nilẹ Yoruba, ọrọ buruku ti Oloye Oluṣegun Ọṣọba ti i ṣe gomina ipinlẹ Ogun nigba kan sọ ranṣẹ si aṣaaju Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjo, ti da wahala silẹ o, nitori ọpọlopo wọn ni wọn ko fara mọ ohun ti Ọṣoba ṣe rara, wọn ni ki i se oun lo yẹ ko bu Adebanjo ni gbangba, ati pe ọro na ayo fa Yoruba sẹyin gan-an ni.

Ọṣọba ba awọn oniroyin Vanguard sọrọ ni, nibẹ lo si ti bẹrẹ si i tu bii ejo, ọrọ to si fi bẹre paapaa le koko ni. O ni, “Mo fẹẹ fi akoko yii kilọ gidigidi fun Oloye Ayọ Adebanjọ pe ọwọ ti mo n fun un nitori iye ọjọ diẹ to gba lọwọ mi lọjọ-ori, ko ni si iyẹn mọ o, bo ba ti ju ogulutu lu mi bayii, emi naa yoo sọ okuta fun un ni, faya-fọ-faya la o jọ maa ṣe fun ara wa. N ko ni  gbe ẹnu mi fun alagbafọ mọ bayii, ohun to ba gbe wa ni mo maa da pada fun un!”

Ohun ti wọn beere lọwọ Ọṣoba ni pe Adebanjo n fẹsun kan oun ati Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu pe awọn ni wọn ko fẹ ki Yoruba gba ara wọn lọwọ awọn amunisin, awọn naa ni wọn fọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, bẹẹ ni oloṣelu marimajẹ ni wọn! Ọrọ yii lo ka Ọṣọba lara to fi sọ pe ki Baba Adebano ma sọro soun mọ o, nitori oun ko si ninu awọn to sọ di gomina, oun ti n ṣe oṣelu oun tipẹ ki oun to mọ Adebanjọ. Ọṣọba ni Adebanjọ funra ẹ lo fọ ẹgbe Afẹnifẹre nipa iwa agidi ati arankan ẹ to maa n hu, to jẹ ki i fẹ ki ẹnikẹni ba oun jiyan, to ti ro pe ohun ti oun ba sọ ni gbogbo aye gbọdọ ṣe.

“Ọpọ igba ni mo ti maa n sọ pe iwa Adebanjọ ko ba ti Awolọwọ mu, nitori Awolọwo maa n gbọ ti ẹlomi-in mọ tiẹ, mo si ti maa n sọ pe ko yee ro pe oun loun ko gbogbo ọgbọn ati imọ Awolọwọ sinu. Lati kekere, ni 1966, ti Awolowo jade lẹwọn ni mo ti mọ ọn, mi o si fi i silẹ titi to  fi ku. Ṣugbọn Adebanjọ ko fẹran mi. Nigba ti won fẹẹ fi mi ṣe olori ileeṣẹ Dailty Times ni 1984, niṣe lo ni ki Awolọwọ ma jẹ ki wọn fi mi ṣe e, ki Awolowo too fi aṣse si i. Igba ti mo fẹẹ ṣe gomina ni 1990, o ni Afọlabi Ọlabimtan ni ki wọn mu, ki n too bori gbogbo wọn. Bẹẹ naa ni ni 1999 to jẹ Fẹmi Okurounmu lo ni awọn Afẹnifẹre gbọdọ ti lẹyin. Ohun ti mo ṣe n sọ pe ko sigba kankan ti Afẹnifẹre ti mi lẹyin lati di gomina niyẹn. Emi o si ninu awọn to sọ di gomina, bẹẹ ni ki i ṣe oun lo mu mi mọ Awolọwo, ko si ihalẹ kankan to le ṣe lori mi.”

“Emi nikan kọ ni mo fi Afẹnifẹre wọn silẹ, gbogbo awa ta a ba ti jẹ gomina ni Adebanjọ maa n koriira. Ṣebi Niyi Adebayọ, gomina Ekiti tẹlẹ, naa binu kuro laarin wọn ni. Bẹe ni Bisi Akande, bẹẹ ni Lam Adeṣina, nitor iwa ojugangan ati aiki-i-gbọ-tẹlomi-in-mọ-tẹni to ti wa lara Adebanjọ. To ba sọ pe awa n tẹle Buhari bayii, a n tẹle Fulani, tabi pe a ki i duro soju kan nidi oṣelu, oun naa nkọ? Abi ki i ṣe oun lo n tẹle Gbenga Daniel, ọmọ PDP, kiri nigbai ti iyẹn di gomina, to kuro nibẹ to lọọ ba Ṣẹgun Mimiko ninu ẹgbẹ Labour, to fi iyẹn silẹ to lọọ ba Ṣeyi Makinde ninu PDP, bẹẹ lo te le Oyinlọla naa titi. Abi nigba ti oun naa n tẹle Atiku kiri, k mọ pe Fulani ni Atiku ni!”

Bi awọn ọrọ naa ti n jabọ niyi, o si han pe Oluṣẹgun Ọṣọba ko fẹẹ ṣe kinni kan ku lai sọ fun baba Adebanjọ. Ohun ti awọn mi-in tori ẹ binu ree. Wọn ni eyi ti Ọṣoba sọ pe ọjọ diẹ lo wa laarin oun ati Adebanjọ ko ri bẹẹ rara, nitori o kere tan, ọdun mọkanla ni baba naa fi ju u lọ. Ati pe ọpọ ọrọ to n sọ ki i ṣe bẹe lo ṣe jẹ, o kan wa aaye kan lati fi sọ oko ọrọ ranṣẹ si ọkan ninu awọn aṣaaju Yoruba naa ni.

Baba Ayọ Adebanjọ paapaa ti sọrọ, o ni oun ko ti i ni fesi si ọrọ Ọṣọba bayii, nigba ti oun ba ṣe tan, gbogbo aye yoo mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an. Ọrọ naa ko fi ọkan awaọn agbaagba ilẹ Yoruba balẹ, ati awọn ọdọ paapaa ati awọn ti n ja fun iṣọkan, wọn ni ohun ti yoo mu ifasẹyin nla ba ilẹ Yoruba ni.

Leave a Reply