Dada Ajikanje
Ni agọ ọlọpaa Festac l’Ekoo ni ọkunrin ọmọ Ibo kan ti n wo pakopako bayii, lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ nibi to ti n fi ika ro ọmọ ọdun marun-un labẹ.
Nnamadi Emdriuokhe, ni wọn pe orukọ ẹ, agbegbe Festac, l’Ekoo gan-an niṣẹlẹ ọhun ti waye. Wọn lo pẹ ti ọkunrin ọmọ Ibo yii ti maa n ra ounjẹ lọwọ iya ọmọ to n ṣe iṣekuṣe pẹlu ẹ yii.
ALAROYE gbọ pe, nibi to ti n fika ro ọmọ naa labẹ ni ẹjẹ ti bẹrẹ si jade, n lawọn eeyan ba ki i mọle, ti wọn si bẹrẹ si i lu u bii ẹni maa ku!
Ọkunrin kan lagbegbe naa, Ọlagunju ̀Ọladele, ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ lo gbe e sori ẹrọ alatagba, ohun to si kọ sibẹ ni pe, ṣọja kan lo gba a kalẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn fẹẹ lu u pa, nigba tọwọ tẹ ẹ.
O ni lojuẹsẹ naa lawọn obi ọmọ ọhun ti fọrọ ọhun to teṣan ọlọpaa leti, ṣugbọn ti awọn yẹn naa tun n beere owo lọwọ wọn, ki wọn too le gba ọrọ wọn silẹ.
Siwaju si i, o ni, nibi ti ọkunrin to hu iwa ọdaran yii ti fẹẹ fowo bọ awọn eeyan ọhun ninu loun ti dide sọrọ ọhun, oun si ti gbe e lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Festac bayii.