Habeeb gun eeyan meji pa nibi ti wọn ti n la oun ati ọrẹ ẹ nija n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Arakunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Habeeb Ganiyu, ti n kawọ pọnyin rojọ ni iwaju adajọ bayii fẹsun pe o gun awọn ọkunrin meji kan, Lukman ati Kudus, lọbẹ pa lasiko ti wọn n laja fun oun ati Abdulateef Abdulrazaq, ti wọn dijọ n ja lagbegbe Gambari, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe lasiko ti afurasi Habeeb ati ẹni keji rẹ Abdulateef, n ja lọwọ ni awọn oloogbe mejeeji, Lukman ati Kudus, ko si wọn laarin lati laja. Ni kete ti wọn la wọn tan ni Habeeb sare lọ sile, o lọọ mu ọbẹ, ko too de, Abdulateef ti wọn jọ n ja ti lọ, o si gun awọn mejeeji to laja fun wọn lọbẹ lọrun, ti wọn si gba ibẹ lọ si ajule ọrun lai ro lojiji.
Majistreeti Abdulraheem Bello paṣẹ pe ki wọn sọ ọ si ahamọ lọgba ẹwọn, o sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Leave a Reply