Happiness tawọn ajinigbe ji l’Ekiti ti gba ominira

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọkunrin kan tawọn ajinigbe ji lọjọ ọdun Keresi, Happiness Ajayi, ti gba ominira lọwọ awọn ẹruuku ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Happiness ati mọlẹbi ẹ kan, Oluwaṣeun Fatile, ko sọwọ awọn oniṣẹ laabi ọhun loju ọna Iṣan-Ekiti si Iludun-Ekiti, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, lasiko ti wọn n lọ siluu Ẹda Oniyọ toun naa wa l’Ekiti.

Oju ọna yii kan naa lawọ̣n ajinigbe ti ji Komiṣanna feto ọgbin nipinlẹ naa, Fọlọ̣runṣọ Ọlabọde, gbe ti wọn si pa kanṣẹlọ to wa mọto ọhun, Ọlatunji Ọmọtọshọ, loṣu kẹrin, odun yii.

Ọkọ jiipu Lexus kan ni Happiness ati Oluwaṣeun gbe kawọn eeyan naa too deede yọ si wọn lojiji, bi wọn si ṣe fẹẹ sare dari ọkọ naa pada lawọn mi-in yọ si wọn lati ẹyin, ti wọn si da ibọn bolẹ. Ọkọ kan to wa lẹyin atawọn to wa lagbegbe naa la gbọ pe wọn sare pe ikọ Amọtẹkun, tawọn yẹn si ri Oluwaṣeun gba silẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa lawọn ajinigbe ọhun kọkọ beere fun miliọnu lọna ọgọrun-un naira, ki wọn too din in si miliọnu mẹwaa, eyi to pada di miliọnu meji. Inu igbo kan ni Isapa, nipinlẹ Kwara, la gbọ pe wọn ti fi i silẹ ni nnkan bii aago meji ọsan.

Nigba to n sọrọ lori bi wọn ṣe fi Happiness silẹ, adari ikọ Amọtẹkun l’Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlaf̣e, sọ pe lẹyin tawọn le awọn ajinigbe naa fun ọjọ mẹta ni wọn fi i silẹ.

O ni ko sẹni to sanwo fawọn eeyan naa, agbara ju agbara lọ ni wọn ṣe fẹsẹ fẹ ẹ.

Bakan naa ni Happiness funra ẹ sọ pe awọn rin lati ọjọ Keresi naa ti i ṣe ọjọ Ẹti to kọja, awọn si rin ninu igbo di aago meji oru ọjọ Satide, bẹẹ ni wọn ko fun oun lounjẹ.

O ni awọn mẹfa lo ṣiṣẹ ibi ọhun, ọkan ninu wọn lo si gbọ oyinbo diẹ, Hausa lawọn to ku n sọ, wọn si n dunkooko pe toun ba fun wọn ni wahala, awọn yoo gbe oun lọ si ipinlẹ Zamfara.

Leave a Reply