Hassan ati Clement tẹle kọsitọma lati banki to ti lọọ gbowo, wọn si ji owo ẹ lọ

Faith Adebọla
Ibi ti wọn ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ, lakolo ọlọpaa, lawọn gende meji kan, Clement Amos ati Hassan Isyaku, wa lasiko yii. Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) ti kọsitọma banki kan ṣẹṣẹ lọọ gba ni wọn ji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdulahi Haruna Kiyawa, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe ni nnkan bii aago mọkanla owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lawọn gba ipe pajawiri kan lori aago, kọsitọma banki kan fẹjọ sun pe wọn ti ti ji owo toun ṣẹṣẹ lọọ gba ni banki lọ.
Ẹni naa ṣalaye pe owo toun fẹẹ fi sanwo-oṣu fawọn oṣiṣẹ oun ti wọn n ṣiṣẹ nileewe Islamiya School Teachers, loun lọọ gba ni ẹka banki UBA Sharada Quarters, niluu Kano. Beeli marun-un ti ọkọọkan rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira lowo naa, oun si di i sinu lailọọnu dudu kan, oun fi rọba de e mọ ẹyin ọkada toun gbe wa.
O ni boun ṣe n lọ si adugbo Ganduje Sharada, oun ya ileetaja lati ra awọn ọja kan, oun ko si pẹ nibẹ rara, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ foun pe boun ṣe jade, lailọọnu toun di owo si ti poora lori ọkada toun de e mọ, ọkada nikan loun n wo lori iduro, loun ba figbe ta.
Wọn ni kia tawọn ọlọpaa ti gbọrọ yii ni wọn ti ke sawọn ọtẹlẹmuyẹ ti ikọ Operation Puff Adder, ni wọn ba bẹrẹ si i tọpinpin awọn to huwa buruku naa, ọwọ si ba wọn.
Awọn afurasi naa jẹwọ pe awọn lawọn ji owo yii, ṣugbọn awọn o ti i na an, wọn si ti ko owo naa fawọn ọlọpaa lodidi. Wọn tun ṣalaye pe iṣẹ adigunjale lawọn n ṣe, ṣugbọn awọn o ki i fọle ni tawọn, awọn ibudo ti wọn n ri ẹrọ ipọwo ATM mọ lawọn ti n jale, nigba tawọn si fura pe owo ni kọsitọma naa lọọ gba lọjọ ọhun lawọn ṣe tẹle e, igba to si jẹ ẹyin ọkada lo de owo naa mọ, bo ṣe wọ ile-itaja lọ lawọn ti palẹ owo rẹ mọ.
Ṣa, Hassan ati Clement ti wa lakata awọn agbofinro, iwadii si n tẹsiwaju, ki wọn too foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply