Hassan, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, yọ oju Yunusa, o ni oogun afẹẹri loun fẹẹ fi ṣe

Faith Adebọla

Bi ki i baa ṣe kọmiṣanna ọlọpaa lo sọrọ ọhun ninu atẹjade to fi lede ni, eeyan iba jiyan pe irọ ni, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ gidi ni, ọmọọdun mẹtadinlogun kan, Issa Hassan, lorukọ ẹ, niṣe lo fi ọbẹ yọ ẹyinju ọtun onibaara kan, o loun fẹẹ fi i ṣe oogun afẹẹri, ẹni to si fẹẹ ba oun ṣe sọ pe ẹyinju eeyan lawọn maa fi ṣe e.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano, Sama’ila Shu’aibu Dikko, ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ ninu atẹjade kan ti Alukoro rẹ, SP Abdullahi Haruna Kiyawa, fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ oṣu Kẹta, ọdun yii. O ni nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju mẹwaa ọsan ogunjọ, oṣu Kẹta, lẹnikan waa ta awọn ọlọpaa lolobo lati adugbo Sheka Dantsinke, nijọba ibilẹ Kumboso, ni Kano, pe ẹnikan mu ọmọọdun mejila to n ṣagbe jẹun kan, Mustapha Yunusa, lọ si kọtaasi Rimin Hamza, nijọba ibilẹ Tarauni, awọn o mọ onitọhun o, ṣugbọn ẹni naa lo yọ oju ọtun Yunusa lọ.
Loju-ẹsẹ ni kọmiṣanna ọlọpaa ti ranṣẹ si ikọ ọlọpaa Puff Adder, eyi ti CSP Alfa Mohammad n dari, pe ki wọn lọọ sibi iṣẹlẹ naa.
Awọn ọlọpaa naa lọ taara si ileewosan Muritala Mohammed Specialist Hospital, nibi ti wọn ni Yunusa ti n gba itọju pajawiri lọwọ, dokita si fidi ẹ mulẹ fun wọn pe ayẹwo ti fihan pe niṣe ni wọn fi nnkan ẹlẹnu ṣoṣoro yọ ẹyinju rẹ lọ.
Awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, awọn fijilante adugbo naa si darapọ mọ wọn, ko si pẹ rara ti wọn ri afurasi ọdaran to ṣiṣẹ laabi naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, Isah Hassan lo porukọ ara ẹ, ọmọọdun mẹtadinlogun pere ni, o laduugbo Dantsinke, lẹyin Rimin Hamza, loun n gbe.
Nigba ti wọn bi i leere bọrọ ṣe jẹ, afurasi ọdaran naa jẹwọ pe ọrẹ oun, Sani Abdulrahman, ọmọọdun mẹrindinlogun pere, loun bi leere ibi toun ti le ri oogun afẹẹri to daju, to le jẹ koun poora nibikibi ati nigbakuugba toun ba fẹ.
O ni Sani lo mu oun lọ sọdọ iyaagba rẹ, Furera Abubakar, ti wọn jọ n gbe. Mama arugbo ẹni ọgọrun-un ọdun yii lo ni koun lọọ wa ẹyinju eeyan wa, oun aa ba a fi ṣe oogun afẹẹri.
O lẹyinju yii loun n wa toun fi ronu kan onibaara to n ṣe alimọjiri (Almajiri) laduugbo awọn, oun si tan an lọ sinu igbo ṣuuru ti ko fi bẹẹ jinna saduugbo naa, oun fokun so o lọwọ mejeeji sẹyin, oun si fi ọbẹ yọ oju ọtun rẹ.
O loun mu ẹyinju naa lọ fun Furera, ni wọn ba sọ foun pe koun lọọ wa ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) wa, ṣugbọn oun ko lowo lọwọ, n ni Furera ba sọ foun pe koun ṣi lọọ tọju ẹyinju naa pamọ titi toun fi maa ri ẹẹdẹgbẹta Naira mu wa.
O ni nigba toun de ibi toun tọju ẹyinju naa si lọjọ kẹta, oun ri i pe o ti jẹra, o ti pinyinkin, o si ti n run buruku buruku, loun ba sọ ọ nu.
Ṣa, wọn ti fọlọpaa mu Furera to fẹẹ ba wọn ṣoogun afẹẹri naa, awọn mejeeji si ti wa lakolo ọlọpaa. Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ ki wọn taari wọn si ẹka ti wọn ti n ṣofintoto iru iwa ọdaran bẹẹ, o lawọn maa wọ gbogbo wọn dele-ẹjọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply