Hausa ti lanlọọdu gba sile gun un pa nitori ọrọ ti ko to nnkan n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii ni wọn ṣi n wa tẹnanti kan to jẹ ẹya Hausa to gun lanlọọdu rẹ pa ni Opopona Agbọ, Iyana Ṣọọṣi, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ọrọ titọju ayika inu ile ti ọkunrin naa n ya gbe lo da wahala silẹ laarin lanlọọdu ati tẹnanti yii. Ọrọ naa lo si fa ariyanjiyan laarin awọn mejeeji. Nigba ti awọn to wa nitosi yoo fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ayalegbe ti wọn pe ni Mọla naa ti fa ọbẹ yọ, lo ba gun lanlọọdu rẹ.

Oju-ẹsẹ ni baba ti ko lomi lara rara naa ṣubu lulẹ. Awọn eeyan kọkọ ro pe o daku ni, afi bi baba naa ko ṣe le dide nibi to wo lulẹ si, ti ẹjẹ si n ya lara rẹ bii omi.

Wọn ko ri ẹmi baba naa du rara, oju-ẹsẹ lo dagbere faye.

Koju ma ri’bi, gbogbo ara loogun rẹ, ni ọkunrin Hausa naa fọrọ ọhun ṣe nitori ko duro wo ohun to ṣẹlẹ si baba naa to fi sa kuro laduugbo ọhun lasiko tawọn eeyan n ṣaajo lanlọọdu naa.

Nigba ti awọn araadugbo tinu n bi yoo fi wo raaraara pe ki wọn da sẹria fun ọkunrin Hausa naa, wọn ko ri i.

Titi ta a fi kọ iroyin yii tan ni wọn ṣi n dọdẹ rẹ.

Leave a Reply