Hiadirẹsa to lọọ woṣẹ lọdọ Samson lo fipa ba lo pọ l’Ọja-Ọdan

Gbenga Amos, Ogun

Iṣẹ woṣẹwoṣẹ, iṣẹ babalawo, lawọn eeyan mọ Ọgbẹni Samson Ogundele mọ l’Ọja-Ọdan, tawọn eeyan si n lọọ ṣe aajo lọdọ ẹ, ṣugbọn aajo ti ọmọbinrin hiadirẹsa kan ba lọ sọdọ ẹ ti gbẹyin yọ, niṣe ni Samson ki onibaara ẹ mọlẹ, lo ba ko ibasun tipatipa fun un, iṣẹlẹ ọhun si ti sọ ọ dero ahamọ ọlọpaa bayii, tori wọn ti mu un.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọrọ yii di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje yii, DSP Oyeyẹmi Abimbọla ni awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ọja-Ọdan, lo lọọ mu afurasi ọdaran yii lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii kan naa, latari ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.

Ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ti babalawo yii fipa ṣe ‘kinni’ fun, lo mu ẹjọ rẹ lọ si teṣan, o ni ẹgbẹrun kan Naira lo sọnu ninu ṣọọbu toun ti n kọṣẹ hiadirẹsa, awọn mẹsan-an si lawọn wa n kọṣẹ lọdọ ọga awọn, ko sẹni to jẹwọ pe oun loun mu owo naa, olowo si n fẹsun ole kan gbogbo wọn.

Ṣe wọn ni bo ba ru ni loju, aa bi ilẹ leere, eyi lo mu ki gbogbo wọn ko ara wọn lọ sọdọ babalawo ọdaran yii, wọn ni ko ba awọn gbe Ifa janlẹ, ki ẹlẹrii-ipin taṣiiri ẹni to huwa afọwọra naa laarin awọn.

Samson ni ẹẹdẹgbẹrin Naira (N700) loun maa gba lọwọ wọn, wọn si san an, lo ba ni ki gbogbo wọn duro sita o, ọkọọkan loun yoo maa pe wọn wọle, toun yoo si maa difa fẹnikọọkan wọn, titi tifa yoo fi tọka gbewiri ọhun.

Ọmọbinrin yii ni ẹni kin-in-ni wọle, o jade, ẹni keji naa lọ bẹẹ, o jade, ṣugbọn nigba to kan oun toun jẹ ẹni kẹta, niṣe ni babalawo yii bẹrẹ si i fa aṣọ mọ oun lọrun, to si fẹẹ fipa bọ pata nidii oun, loun ba tu jade bii ejo mọ ọn lọwọ, lo ba lọọ fẹjọ ẹ sun ni teṣan ọlọpaa.

Kia ni wọn ti mu Samson adifala ọran yii, nigba ti wọn si bẹrẹ si i wadii ọrọ lẹnu ẹ atawọn to waa woṣẹ ọhun ni ọkan ninu wọn, ọmọbinrin ọmọọdun mẹtadinlogun kan, jẹwọ pe nigba toun wọle lọjọ naa, babalawo yii ko gbe Ifa kankan janlẹ, kaka bẹẹ, ẹyin oun lo mu balẹ, niṣe lo fipa ba oun laṣepọ.

O ni loootọ loun o sọ nnkan kan nigba toun jade, tori o ti kilọ foun pe wiwo lẹnu awo n wo, toun ba fi sọrọ jade pẹnrẹn, iku ati aisan nla lo maa kọ lu oun.

Wọn mu ọmọbinrin naa lọ si ọsibitu Jẹnẹra Ọja-Ọdan fun ayẹwo, awọn oniṣegun si fidi ẹ mulẹ pe loootọ lẹnikan ti fipa ṣe ibalopọ ọran fọmọ ọhun.

Nigba ti gbangba si ti dẹkun, Samson jẹwọ, o ni iṣẹ eṣu ni, loootọ loun huwa ainitiju ọhun.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe paṣẹ. Tawọn ọtẹlẹmuyẹ ba pari iwadii ni wọn yoo taari afurasi ọdaran yii sile-ẹjọ.

Leave a Reply