Hijaabu: Awọn mẹrin fara pa lasiko ti awọn Kristiẹni ati Musulumi kọju ija sira wọn n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọrọ lilo ibori ta a mọ si hijaabu lawọn ileewe Kristẹni to ti n da wahala silẹ lati ọsẹ diẹ sẹyin tun gbọna mi-in yọ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba tawọn ẹlẹsin Kristẹni, paapaa ijọ Onitẹbọmi, Baptist atawọn Musulumi koju ija sira wọn niluu Ilọrin, eeyan mẹta lo fara pa nibẹ.

Kinni ọhun to bẹrẹ wẹrẹ-wẹrẹ ti fẹẹ maa di ija ẹsin laarin igun mejeeji.

Ṣe lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nijọba kede ki wọn ṣi gbogbo awọn ileewe mẹwẹẹwa to wa ni titi, ki awọn akẹkọọ si maa ba ẹkọ wọn lọ.

Ṣugbọn nigba to di nnkan bii aago mẹjọ aabọ si mẹsan-an aarọ Ọjọruu, ṣe lawọn ẹlẹsin Kristẹni lọọ di abawọle ileewe girama Baptist ati alakọọbẹrẹ, lati ma gba akẹkọọ-binrin kankan pẹlu hijaabu lati wọle.

Ṣe lawọn eeyan ọhun gbe oriṣiiriṣii akọle lọwọ, ti wọn n fi ẹhonu han ta ko aṣẹ ijọba lori ọrọ hijaabu naa.

Lara akọle naa ni; “O to gẹ, da ileewe wa pada fun wa”, “Ko si aaye fun wiwọ hijaabu lawọn ileewe wa” ati bẹẹ lọ.

Bawọn ti ẹlẹsin Kristẹni ṣe gbe akọle wọn lọwọ niwaju ileewe ọhun, bẹẹ lawọn ti Musulumi naa duro ni isọda keji pẹlu tiwọn.

Nibi ti wọn ti n pariwo mọ ara wọn lawọn kan ti wọn fura si si pe wọn jẹ Musulumi ya bo awọn olufẹhonu han naa, ti ọrọ si dija igbooro.

Awọn agbofinro bii ajọ NSCDC, ọlọpaa digboluja atawọn ṣoja lo sare gba gbogbo agbegbe naa kan lati pana ija naa.

ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa fi ado taju-taju le awọn olufẹhonu han naa danu.

 

Leave a Reply