Hijaabu: Ijọba yi ipinnu rẹ pada, o ni kawọn ileewe mẹwaa ṣi wa ni titi n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Nitori wahala tọrọ lilo ibori ta a mọ si hijaabu laarin awọn akẹkọọ-binrin Musulumi n da silẹ nipinlẹ Kwara, ijọba ti yi ipinnu rẹ pada lori ṣiṣi awọn ileewe mẹwaa kan to ti lati bii ọsẹ meji sẹyin, o si ti paṣẹ lọjọ Aje, Mọnde, pe kawọn ileewe ọhun ṣi tẹsiwaju lati maa wa ni titi di ọjọ mi-in ọjọ ire.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nijọba ti kede pe awọn ileewe ọhun yoo di ṣiṣi pada, ṣugbọn oun fi aṣẹ si lilo hijaabu lawọn ileewe to jẹ tajọ ẹlẹsin kristẹni naa.

Aṣẹ tijọba pa naa ko dun mọ ajọ CAN atawọn alaṣẹ ileewe tawọn ṣọọṣi da silẹ, wọn ta ku pe awọn ko ni i gba hijaabu laaye lawọn ileewe wọn.

Atẹjade kan lati ọdọ akọwe agba nileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ, Arabinrin Kẹmi Adeọṣun, ni ijọba gbe igbesẹ lati ti awọn ileewe naa pa nitori aabo awọn akẹkọọ to n lọ sawọn ileewe mẹwẹẹwa ti ọrọ lilo hijaabu ti da ruke-rudo silẹ naa.

Adeọṣun ni, awọn ileewe ọhun ni; C&S College Sabo Oke, St. Anthony College, Offa Road, ECWA School, Ọja Iya, Surulere Baptist Secondary School, Bishop Smith Secondary School, Agba Dam, CAC Secondary School Asa Dam road, St. Barnabas Secondary School Sabo Oke, St. John School Maraba, St. Williams Secondary School, Taiwo Isale, ati St. James Secondary School Maraba.

Ijọba ti waa kede pe ki gbogbo awọn olukọ atawọn akẹkọọ ileewe mẹwẹẹwa wa nile wọn titi tawọn ileewe naa yoo fi di ṣiṣi pada.

 

 

Leave a Reply