Hijrah 1443 AH: Gomina Oyetọla kede ọjọ Aje ni ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ

Florence Babaṣọla

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fi ṣajọyọ ọdun Hijrah 1443 AH.

Eleyii jẹ yọ ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna to n mojuto ọrọ abẹle (Commissoner for Home Affairs) nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Tajudeen Ọlaniyi Lawal, fi sita laipẹ yii.

Oyetọla ba awọn Musulumi yọ fun ayajọ ayẹyẹ Hijrah ti ọdun yii, o si rọ wọn lati lo asiko ọlude naa lati fi gbadura fun idagbasoke ipinlẹ Ọṣun ati orileede Naijiria lapapọ.

Bakan naa lo rọ wọn lati ma ṣe gbagbe gbogbo alakalẹ idena itankalẹ arun Koronafairọọsi nibikibi ti wọn ba wa.

Leave a Reply