Hisbah gbẹsẹ le ọti bia to din diẹ lẹgbẹrun mẹfa ni Kano

Ọti bia to din diẹ lẹgbẹrun mẹfa katinni (5,760 cartons), ni ikọ ọlọpaa Sharia ni Kano, Hisbah, gbẹsẹ le l’Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an yii, nigba ti tirela meji fẹẹ ko awọn ọti oriṣiiriṣii ọhun wọ ilu Kano.

Nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ naa ni ikọ Hisbah da awọn tirela meji to ko ọti ọhun duro, ti wọn si fi agbara ofin mu wọn, ti wọn ko jẹ ki wọn lọọ pin awọn ọti naa sigboro lọdọ awọn oniṣowo rẹ.

Ọga agba Hisbah, Dokita Harun Ibn-Sina, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita latọwọ alukoro rẹ,  Lawan Ibrahim, pe eewọ ni ọti mimu ni Kano, nitori awọn ko fẹ ohun ti yoo maa pa awọn eeyan tabi ti yoo maa mu wọn ṣe werewere.

O ni ki i ṣe ọti mimu nikan o, atawọn oogun oloro to n mu eeyan ṣe lodilodi ai (high)  pẹlu. O lawọn yoo maa gbe ogun ti wọn bi wọn ba wọlu naa wa, ko ni i de ọdọ awọn to fẹẹ lo o tawọn yoo fi gbẹsẹ le e

Ọga Hisbah naa gboriyin fawọn oṣiṣẹ rẹ to tete gbegi dina ọti rẹpẹtẹ to fẹẹ wọ Kano wa naa, o ni igbogunti iwa ibajẹ laarin awọn ọdọ ko ni i duro, yoo maa lọọ bẹẹ ni.

Leave a Reply