Iṣẹ ni ọmọkunrin yii fi tan akẹkọọ-jade fasiti, to si pa a sinu igbo lẹyin to fipa ba a lo pọ tan

 Faith Adebọla

Agba adura ni ti wọn ba n sọ pe ‘a n wa ohun ti a oo jẹ lọ, ka ma pade ohun ti yoo jẹ wa.’ Adura yii lo ṣe kongẹ iṣẹlẹ ọmọbinrin akẹkọọ-gboye Fasiti Uyo ti wọn porukọ ẹ ni Umoren Iniubong, nipinlẹ Akwa Ibom yii.

Ọsẹ to kọja yii ni lawọn ẹbi kede pe awọn n wa ọmọbinrin naa, wọn lo dagbere nile pe oun fẹẹ lọọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo (interview) fun iṣẹ kan ti wọn pe oun si, ṣugbọn niṣe lafurasi ọdaran to pe ọmọ naa lori aago ki ọmọbinrin yii mọlẹ, o fipa ba a lo pọ, o si pa a lẹyin ti to ṣe tan, o wa koto kuṣẹkuṣẹ kan lẹhinkule ile baba ẹ, o si bo oku ẹ mọlẹ nibẹ.

Iṣẹlẹ to gbomi loju eeyan yii di tọlọpaa, nigba tawọn mọlẹbi ko ri ọmọ wọn, ti wọn o si mọ ohun to ṣẹlẹ si i, lawọn ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ ọhun ba bẹrẹ si i finmu finlẹ.

Lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ni gudugbẹ ja, ọlọpaa lawọn ti ri oku ọmọbinrin naa nibi ti wọn sin in si, ọwọ wọn si ti tẹ amookunṣika to ṣiṣẹ laabi ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, Ọgbẹni Odiko MacDon, sọ pe afurasi ọdaran ẹni ogun ọdun kan, Uduak Akpan, lo huwa ọdaju naa. Wọn ni apanijaye ni, ko ṣẹṣẹ maa ṣeru ẹ.

Ninu atẹjade to fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, o sọ pe:

“Ọgbọn ọjọ, oṣu kẹrin to kọja yii, nileeṣẹ ọlọpaa gbọ pe ọmọbinrin kan, Umoren, ti dawati, la ba ṣeto fawọn ikọ ọlọpaa to n ri si iṣẹlẹ ijinigbe lati ṣiṣẹ lori ẹ, CSP Inengiye Igosi lo ṣaaju ikọ naa.

Lẹyin ti wọn ti fimu finlẹ daadaa, olobo ta wọn, wọn si tọpa iṣẹlẹ naa de ile afurasi ọdaran to huwa laabi ọhun, wọn ba a nile, wọn si fi pampẹ ofin gbe e.

Lagọọ ọlọpaa, wọn lo jẹwọ pe oun loun pe oloogbe naa lori aago rẹ pe ko waa ṣe intafiu fun iṣẹ to loun n wa. O ni ile oun loun juwe fun un, inu yara oun si loun ti fipa ba a lo pọ, tori ko sawọn eeyan nile lasiko naa, gbogbo adugbo naa si ti da. O ni ọmọbinrin naa ko gba foun bọrọ, eyi lo jẹ koun lu u, toun si fun aṣọ mọ ọn lọna ọfun ko ma le pariwo fun iranlọwọ.

Wọn lo tun ṣalaye pe boun ṣe n ba a lo pọ lọwọ loun ṣakiyesi pe ko mira mọ, oun si gbo o jigijigi, oun ri i pe o ti dakẹ. Eyi lo mu koun tete wa ibi kan lẹyinkule ile awọn, toun si sare gbẹ ilẹ, oun sinku ẹ sibẹ kawọn eeyan too fura.

Awọn ọlọpaa lawọn ti lọọ hu oku naa jade, awọn si ti gbe e lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa niluu Uyo, fun ayẹwo.

Wọn ti taari afurasi apaayan yii si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran.

Leave a Reply