Iṣẹ ọlọpaa bọ lọwọ Felix l’Oṣogbo, ọlọpaa ẹgbẹ ẹ lo ja lole

Olajide Kazeem

Iṣẹ ti bọ lọwọ ọlọpaa ọmọ odun mẹrinlelogun kan, Felix Ọlayiwọla, foonu alagbeeka lo ji gbe, n ni wọn ba gbe e lọ si kootu, lẹyin ti wọn gbaṣẹ lọwọ ẹ.

Ile-ẹjọ kan niluu Oṣogbo lo ti n kawọ pọnyin rojọ bayii lori ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọkunrin kan, Bọlaji Ajiboye, to n waṣẹ ọlọpaa ni wọn sọ pe o ni ẹrọ ibanisọrọ naa, iyẹnTechno Camon 12, tiye ti wọn n ta a jẹ ẹgbẹrun mejidinlọgọta naira (N58,000). Bakan naa ni Felix tun ko owo tiye ẹ jẹ ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn naira (N25,000) ninu baagi Bọlaji.

Niwaju Adajọ Modupẹ Awodele ni Ọgbẹni John Idoko, ọlọpaa to wa nidii ẹsun ti wọn fi kan Felix yii ti ṣalaye pe, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ni deede aago mẹjọ aabọ aṣalẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Oṣogbo niṣẹlẹ ọhun waye.

O ni, ninu baagi ti Bọlaji Ajiboye ko awọn dukia ẹ yii si ni Felix tọwọ bọ, to si ji foonu ọkunrin to waa gbaṣẹ ọlọpaa ọhun gbe, to tun ko owo to wa ninu baagi naa pẹlu.

Ọkunrin ti wọn fẹsun kan yii ti sọ pe oun ko jẹbi, bẹẹ ni agbẹjọro ẹ, O.O Ọladele, gbiyanju lati bẹbẹ fun beeli ẹ, ṣugbọn ọlọpaa to wa nidii ẹjọ ẹ sọ pe o ṣee ṣe ko sa lọ ti wọn ba fun un ni beeli ọhun.

Adajọ ti pada fun un ni beeli, bẹẹ lo ni ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro kan.

Igbẹjọ mi-in yoo waye lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun yii.

 

Leave a Reply