Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Niṣe ni ero pe biba si iyana Oduduwa to wa nitosi ileewe olukọni agba Adeyẹmi, niluu Ondo, lati woran were obinrin kan to ṣẹṣẹ bimọ sita gbangba adugbo ọhun lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lai si ẹni to gbẹbi fun un.
Ọkan ninu awọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun, Ọgbẹni Ọlanrewaju Kọlawọle, to ba ALAROYE sọrọ ni lati bii ọdun diẹ sẹyin loun ti maa n ri were naa nitosi agbegbe to pada waa bimọ si yii, ati pe ko sẹni to le sọ akoko ti obinrin alarun ọpọlọ yii bimọ.
O ni funra rẹ lo rọbi, to si gbẹbi ara rẹ lai si iranlọwọ ẹnikẹni. O ni o ti bimọ tan siwaju ṣọọbu kan to wa lẹgbẹẹ ile awọn koun too ri i nibi to jokoo si, to si fi aṣọ akisa jinwin kan we ọmọ tuntun naa nilẹẹlẹ to gbe e ju si.
Ọkunrin yii ni oun loun pe akiyesi awọn araadugbo sohun to n ṣẹlẹ yii ti awọn eeyan fi jade lati waa ṣaajo oun ati ọmọ jojolo ọhun.
Ounjẹ lo ni awọn kọkọ ra fun iya ikoko naa ki ara rẹ le balẹ, lẹyin ti wọn wẹ fun un tan lo ni awọn ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ileewosan Katọliiki to wa lagbegbe Ọka, niluu Ondo, lati waa gbe iya atọmọ lọ fun itọju.
Ninu iwọnba ọrọ ti alarun ọpọlọ yii b’ALAROYE sọ ki wọn too gbe e lọ sile-iwosan la ti fidi rẹ mulẹ pe Deborah lo n jẹ, ati pe ọmọ bibi ilu Idanre ni i ṣe.
Iyawo alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, Abilekọ Amọpe Akinsulirẹ, ti ṣabẹwo si ile-iwosan ọhun, nibi to ti ṣeleri ati ṣe itọju ọmọ tuntun ọhun ati iya rẹ. Bẹẹ lo tun fi asiko abẹwo naa rọ ijọba lati tete wa nnkan ṣe si bawọn eeyan kan ṣe n fipa ba awọn were sun laarin ilu.