Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Oloye Ṣẹgun Oni, ti pe akiyesi ijọba si ipese iṣẹ fawọn ọdọ, ki opin le de ba iwọde to le da wahala silẹ laarin ilu lọjọ iwaju.
Ninu ọro ti gomina tẹlẹ yii ba ileeṣẹ iroyin NAN sọ lo ti fidi ẹ mulẹ pe ọpọlọpọ oṣi, iṣẹ ati iya to n ba awọn ọdọ orilẹ-ede yii finra latari ainiṣẹ gidi lọwọ lo fa sababi bi awọn eeyan kan ṣe ba dukia jẹ, ti wọn tun ṣe ọpọ nnkan lofo.
Oni sọ pe,“Mo ri ọpọlọpọ oju ti ko rẹrin-in rara, inu wọn ko dun, bẹẹ lọkan wọn poruru. Ibanujẹ nla lo jẹ nigba ti mo ri ọpọ awọn ọdọ ti wọn ya soju popo, ti wọn da bii ẹni ti ko si ireti ọjọ ọla gidi fun. Ohun to ba mi ninu jẹ pupọ ni.’’
O ṣalaye pe ọrọ to wa nilẹ bayii kọja rogbodiyan to ṣẹlẹ ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii, nikan, o ni o jọ pe o pẹ ti ọkan awọn mi-in ninu awọn ọdọ yii ti daru, ti wọn si lo anfaani iwọde jẹẹjẹ tawọn kan n ṣe lati fi da wahala rẹpẹtẹ si aarin ilu.
Ifaki Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lo ti sọrọ ọhun. Bẹẹ lo fi kun un pe asiko ti to bayii ti ijọba apapọ gbọdọ mura gidi lati pese iṣẹ lọpọ yanturu. Bakan naa lo sọ pe eto gbọdọ wa lori bi wọn yoo ṣe maa gba wọn ṣiṣẹ pẹlu ilana ẹni to ba tọ fun iṣẹ ọhun dipo lilo ọrọ oṣelu, ẹsin, ojuṣaaju tabi ẹlẹyamẹya kankan.
Ṣẹgun Oni tun sọ pe ijọba ni lati ṣatunṣe si ọrọ awọn ọlọpaa, eyi ti yoo mu igbe aye wọn, ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ, wa ni ibamu pẹlu awọn mi-in kaakiri agbaye.
O ni ti owo-oṣu ọlọpaa ba dara, ko si ki iru ọlọpaa bẹẹ ma ṣiṣẹ ẹ bii iṣẹ, bẹẹ ni alaafia yoo wa laarin ilu pẹlu, ti ohun gbogbo yoo maa lọ pẹlu eto.