Iṣọ-oru niyawo Sunday lọ, lọkọ ẹ ba fipa ba ọmọ ọlọmọ lo pọ ko too de

Faith Adebọla, Eko

 Ọwọ awọn agbofinro Eko ti ba ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Sunday Ukeme, wọn niṣe lo ki ọmọbinrin ọmọọdun mẹtala kan ti wọn fi sọdọ iyawo ẹ mọlẹ, o fipa ba a laṣepọ, nigba tiyawo ẹ lọ si isin iṣọ oru.

Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, fi ṣọwọ s’ALAROYE sọ pe iwadii fihan pe nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye niluu Idasọ, lagbegbe Ibẹju Lẹkki.

Iyawo afurasi ọdaran naa, Abilekọ Mary Sunday ṣalaye fawọn agbofinro pe iya ọmọbinrin naa lo ni koun ba oun mu ọmọ rẹ sọdọ latari irin-ajo kan to loun fẹẹ lọ, to si maa lo to ọsẹ mẹta lọhun-un.

O ni oun o si nile nigba tiṣẹlẹ naa waye, bẹẹ loun o si fura rara pe ọkọ oun ti ni ero buruku bẹẹ lọkan sọmọ ọlọmọ, ti wọn forukọ bo laṣiiri yii.

O ni ṣọọṣi kan to wa laduugbo awọn loun ti lọọ ṣe iṣọ oru lọjọ naa, isin aṣemọju ni, fẹẹrẹ ọjọ keji loun too de.

Ko sẹni to gbọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ ọhun titi ti iya ọmọ naa fi de, oun ni ọmọ ẹ jẹwọ fun, akara tu sepo, niya ba figbe ta. Wọn ni bi wọn ṣe de ọdọ Ukeme, o loun o mọ nipa ẹ, ṣugbọn laarin iṣẹju diẹ, niṣe lo sa lọ, wọn wa a titi, wọn o ri i.

Eyi lo mu iya ọmọbinrin naa gba teṣan ọlọpaa lọ lọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa yii, ẹsẹkẹsẹ lawọn agbofinro si ti wa afurasi ọdaran naa lawaari, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e.

Ni teṣan, afurasi ọdaran naa ko jampata mọ, bi wọn ṣe wi, wọn lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun ṣe kinni fọmọbinrin yii, pe ki wọn ṣaaanu oun, iṣẹ Eṣu ni, ati pe ọti loun mu yo lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, oun o tiẹ mọ nnkan toun n ṣe mọ.

Ṣugbọn ọti ti da loju Ukeme, awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, si ti n ba iṣẹ iwadii wọn lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ni bọrọ afurasi yii ba jẹ mọ aanu tabi bẹẹ kọ, ipade di iwaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply