IṢẸLẸ KAN ṢẸLẸ SI MI NILUU ILỌRIN TO GBOMI LOJU MI-Madam no Network

FAITH ADEBỌLA, MONISỌLA SAKA

Ba a ba n sọrọ nipa awọn adẹrin-in poṣonu nilẹ wa, ọtọ ni tọ́lú, ọtọ ni tọ̀lú, ọtọ si ni tọ́lùú wò ti obinrin kan ti wọn n pe ni Atinukẹ, ṣugbọn ti gbogbo eeyan mọ si Madam no Network.

Adẹrin-in poṣonu ni loootọ, ṣugbọn ọna ara ni oun n gba dẹrin-in pa awọn eeyan. Bo ṣe maa n ṣe bii aditi, ti awọn eeyan yoo maa wi irú, ti oun yoo si maa wi ìrù lo maa n pa awọn eeyan lẹrin-in, nitori ọtọ ni ohun ti wọn yoo maa bi No Network, ọtọ ni ohun ti yoo maa dahun, ko si si bi eeyan ṣe le ya oṣonu to, to ba wa nibi ti wọn ti n bi obinrin naa lọrọ, to si n gbọ bo ṣe n fun wọn lesi, yoo rẹrin-in ṣaa ni.

Laipẹ yii ni ALAROYE ṣabẹwo si obinrin to lomi lara daadaa yii, to si ṣalaye awọn ohun ti ọpọ eeyan ko mọ nipa rẹ. Bawo lo ṣe gba orukọ No Network to ti waa bori orukọ ti iya ati baba sọ ọ? Bawo ni irinajo rẹ nidii iṣẹ tiata, awọn aṣeyọri wo lo si ti ṣe nidii iṣẹ yii? Gbogbo nnkan wọnyi ati awọn ohun mi-in ti ẹnikẹni ko mọ nipa oṣere yii lo tu kẹkẹ rẹ funa awọn akọroyin wa.

Ko sai mẹnu ba iṣẹlẹ kan to gbomi loju rẹ gidigidi niluu Ilọrin.

Eyi lawọn ohun ti arẹwa oṣere naa ba awọn akọroyin wa, FAITH ADEBỌLA ati MONISỌLA SAKA sọ.

 

ALAROYE: Ki lorukọ yin?

Madam No Network: Ẹẹẹhn? Ẹ ni pe?

ALAROYE: Ki ni orukọ yin?

Madam No Network: Ẹ fẹẹ fo fence? ( O rẹrin-in). Orukọ mi ni Atinukẹ ti inagijẹ mi n jẹ Mama no Network, ti gbogbo ẹyin ololufẹ mi dẹ tun mọ si ‘Iya Saburi o n skonto’.

ALAROYE: Ọmọ ilu wo ni yin?

Madam No Network: Mo jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹbu-Ode, Ijẹbu-Ode ni baba to bi mi lọmọ, amọ Agọ-Iwoye ni mama mi.

ALAROYE: Ṣe ibẹ naa lẹ ti ṣe kekere ni?

Madam No Network: Mo ṣe kekere ni Ijẹbu-Ode, ibẹ naa ni mo ti lọ sileewe. Moslem School la maa n pe ileewe yẹn nigba yẹn ni Ijẹbu-Ode. Ibẹ ni mo ti ka iwe mẹfa ja.

ALAROYE: Igba wo lẹ dero Eko?
Madam No Network:
Eko naa ni wọn bi mi si o. A kan lọọ ṣe kekere niluu ni. Idumọta gangan ni wọn bi mi si ni kekere, niluu Eko nibi. Ibẹ lawọn obi mi n gbe, ibẹ ni wọn bi mi si.


ALAROYE: Ṣe iṣẹ tiata yii lẹ n ṣe lati ilẹ ni abi ẹ ni in lọkan lati ṣiṣẹ mi-in?
Madam No Network:
Iṣẹ tiata kọ. Mo ti figba kan kọṣẹẹ telọ ri. Nigba ti ọga mi wa n ko lọ si Ibadan, ti wọn fẹ maa lọọ gbebẹ, ni mi o ṣe kọṣẹ mọ. Amọ iṣẹ telọ ni mo kọkọ kọ.
ALAROYE: Ṣe ẹ dẹ mọ ọn?
Madam No Network:
( O rẹrin-in) Aye igba yẹn, pepa simẹnti la maa n fi n ge aṣọ, mo dẹ ti n ge bulaosi diẹdiẹ nigba naa. Ṣe ẹ dẹ mọ pe abẹrẹ ati owu la kọkọ fi maa n ran aṣọ awọn bebi ta a maa n ran lati fi danra wo nigba yẹn.


ALAROYE: Igba wo lẹ wa
a bọ sori iṣẹ tiata yii?
Madam No Network:
Nnkan to ṣẹlẹ ni pe ni ti iṣẹ tiata, lagbegbe Ṣomolu, nipinlẹ Eko, lọdọ Kalẹyẹwa Theatre Group, ni mo ti kọṣẹ. Bii ijo Ṣango atawọn oniruuru ijo to wa nigba yẹn lọgaa mi kọ mi. Awọn kọ ni wọn kọ mi ni ere awada ti mo n ṣe yii.

ALAROYE: Ki lo mu ọkan yin lọ sidii iṣẹ tiata ko too di pe ẹ ṣẹṣẹ wa lọọ kọ ọ?

Madam No Network: Nnkan to wa lọkan mi ni pe, ki Ọlọrun fọrun kẹ Anti mi, Oriṣabunmi, ṣe ẹ mọ pe awọn maa n sun rara ni. Nigba yẹn, mo maa n wo wọn, mo maa n wo o pe o dẹ wu mi kemi naa maa sun rara bi anti yii ṣe maa n ṣe o. Mo waa lọọ ba baba kan laduugbo wa pe mo dẹ fẹẹ maa sun rara o, o waa ni mo le ma mọ ọn nitori wọn ki i kọ ọ, wọn maa n bi eeyan mọ ọn ni. Wọn ni abi ṣe ọmọ eleegun ni mi ni, mo ni rara, wọn ni ṣe ọmọ Ọlọṣun ni tabi a ni oriṣa kankan ni idile wa, mo ni rara. Ni wọn ba ni mi o le kọ ọ, afi ti n ba kan n gbiyanju ẹ. Latigba yẹn naa ni mo dẹ ti n gbe igbesẹ lati kewi, bi iru yin yii nisinyii, mo le fẹẹ ki yin, nẹtiwọọki kan le sa lọ ti ko ba sowo ni (o rẹrin-in).

Bawo ni ibi ọdọ ọga yin tẹ ẹ ti lọ kọṣẹ ṣe ri, ki lawọn nnkan ti wọn kọ yin?

Madam No Network : Lara awọn nnkan ti wọn kọ wa ni ere ori itage, ọga wa jẹ eeyan kan ti wọn maa n ṣe ere ori itage. Wọn dẹ maa n gbe e kaakiri awọn igberiko. Ṣe ẹ mọ pe ko sohun to n jẹ fiimu nigba yẹn, ṣugbọn a maa n dawo jọ fun awọn LTV ti wọn maa gbe kamẹra waa fi ya wa nigba yẹn, laye ‘roll tape’ kan bayii. Nigba yẹn ṣa, ere ori itage lọgaa mi maa n gba ju, bii ka lọọ ṣere ori itage ni inu awọn ileewe lawọn abule kereje kereje.

ALAROYE: Iyatọ wo lo wa laarin ere ori itage yẹn ati fiimu agbelewo toni?

Madam No Network: Iyatọ wa nibẹ. Laye isinyii, ori ijokoo la maa wa ta a ti maa ṣe ohun ti wọn ba ni ka ṣe. Laye igba yẹn, ori itage ni, wọn maa kan pako, ori ibẹ yẹn la maa duro le lori ṣere. Lara ohun ti wọn kọ wa ni ba a ṣe maa doju kọ awọn ero iworan ta o fi ni i kẹyin si wọn. Gbogbo awọn nnkan wọnyi ni wọn ti fi kọ wa, gbogbo ẹni to ba dẹ kọ ere ori itage yii laye igba yẹn, oun ṣi la n pe ni ọga.

ALAROYE: Ere wo lẹ kọkọ kopa ninu ẹ, ipa wo lẹ si ko ninu ere ọhun?

Madam No Network: Ere ta a kọkọ kopa ninu ẹ, gẹgẹ bi mo ṣe sọ fun yin lẹẹkan pe tẹlifiṣan LTV8 ni wọn maa n gbe kamẹra wa ti wọn maa waa ya wa nigba yẹn, ko dẹ ti i di ohun to fẹju bayii ko too di aye igba ti awọn ọga wa fẹ ẹ loju. Ere ti mo waa mọ pe mo kọkọ ṣe to han diẹ, loootọ mi o ki i ṣere Nẹtiwọọki nigba yẹn, nẹtiwọọki mi o ki i sa lọ nigba yẹn, awọn ere eeyan ti eti ẹ o di ni mo maa n ṣe. Amọ toni nẹtiwọọki yẹn, Ọlọrun kan ṣaa fi sọ pe ọna mi niyẹn ni.

ALAROYE: Ẹ o waa le ranti akọle ere tẹ ẹ kọkọ kopa ninu ẹ?

No Network: Ere ti mo le kọkọ sọ pe mo kopa ninu ẹ to gbajumọ ni ‘Aginju Ibẹru’ ti Tọpẹ Ẹgbẹji ṣe. Ere tawọn iwin n paayan ninu igbo. O kan wa lọjọ yẹn ni mo ni ẹ jọọ, ẹ jẹ k’emi naa ṣe bo jẹ idan (scene) kan pere, bii ere bii ere, ni wọn ba lo ya. Mo dẹ ṣe e, Ọlọrun dẹ ṣe e lati ibẹ.

ALAROYE: Njẹ wọn fun yin lowo nigba tẹ ẹ ṣere yẹn?

Mama No Network: Owo kẹ! Abi mo tun dupẹ pe wọn ṣe e. Ko sowo o, niṣe ni mo tun n dupẹ pe wọn tiẹ lo mi, bo tilẹ jẹ pe ọna kan naa ni.

ALAROYE: Ere wo lẹ kọkọ ṣe tẹ ẹ fi gbowo?

Madam No Network: Walai mi o tiẹ mọ, tori iṣẹ ọfẹ lo pọ ju nigba yẹn, a ki i beere owo, a n ṣe e pe ki wọn le ri wa ni.

ALAROYE: O da bii pe ọrọ bi
i ẹfẹ, bii awada ni ipa tẹ ẹ n ko jẹ mọ, ṣe alawada ni yin latilẹ ni abi ẹ kọ awada yẹn ni?

Madam No Network: Mi o ki i ṣe alawada latilẹ. Mi o dẹ kọ ọ, Ọlọrun kan mọ-ọn mọ fi ọna yẹn han mi ni, nitori nigba ta a lọọ ṣere ori itage yẹn. Wọn ni a maa ṣere babalawo, emi lọ sile babalawo lati lọọ ṣe nnkan. Ni babalawo ba sọ fun mi pe ‘nnkan ti mo ba ti sọ, ko o maa sọ ọ tẹle mi ni o’. Mo ba ni o daa, mo ti gbọ, ni babalawo ba ni ‘ko ti i ya, ani mo sọ pe ko ti i ya, ani ẹ jokoo mama’, lati ibẹ lọ, awọn eeyan wa rẹrin-in, wọn patẹwọ. Mo waa wo o pe ti mo ba dẹ le maa ṣe iru awọn nnkan bayii o, o maa daa, bi mo ṣe bẹrẹ ẹ niyẹn. Ere ori itage la lọọ ṣe nigba yẹn ko too di pe Ọlọrun waa jẹ ko ja sọpẹ. Kawọn eeyan too waa maa ri wa ninu fiimu lẹẹkọọkan.

ALAROYE: Bawo lẹ ṣe waa di Madam No Network?

Madam No Network: Igba ta a ṣe fiimu ‘Misita Tiṣa’, iṣẹ awọn Nice Twins. A waa ṣe ‘Baba Nepa’, ‘Baba Nepa’ yẹn la n ṣe lọwọ ni Latin waa sọ pe ‘eee Iya Mistura, nnkan ti mo fi le rẹrin-in si ohun ti o ṣe yii, mo fẹẹ ṣe fiimu kan ‘Lagos to Benin’, mo maa pe ẹ lati waa kopa nibẹ. Nigba yẹn ni mo waa lọọ ṣe ‘Lagos to Benin’ yẹn, fiimu yẹn ni Epsalum waa fi polowo ti mo fi sọ pe ‘ibi ibi (o fọwọ si eti ẹ apa osi), ko si nẹtiwọọki.

ALAROYE: Ki ni itumọ ibi ibi ko si nẹtiwọọki?

Madam No Network: (o rẹrin-in) Tẹ ẹ ba ti sọrọ daadaa, kẹ ẹ wo oju mi ni. Ẹ wo oju mi, tori tẹ ẹ ba kọju si mi ba mi sọrọ, mo le ma gbọ, amọ tẹ ẹ ba fọwọ ṣapejuwe bayii pe ‘ounjẹ ounjẹ’, ma a gbọ.

ALAROYE: Ṣugbọn loju aye gangan, ṣe nẹtiwọọki wa?

Madam No Network: Haaa, o maa n sa lọ ti ko ba ti si ọrọ owo. Ọrọ ti ko ba ti si owo nibẹ, nẹtiwọọki le sa lọ o, amọ eyi towo ba wa nibẹ, nẹtiwọọki maa wa.

ALAROYE:
Wọn ni ọkọ yin tẹlẹ, Lanko Ọmọọba Dubai, lo kọ yin ni awada?

Madam No Network: Nigba ta a jọ wa yẹn, a dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ohunkohun to ba ti jẹ oro Lanko, mi o ki i sọ ọ lori afẹfẹ. O yẹ ki ọrọ mi ti ye yin. A ti fẹra wa ri loootọ, a o fẹra wa mọ, o ti tan.

ALAROYE: Nigba kan tẹ ẹ ṣe ifọrọwerọ pẹlu ALAROYE gbẹyin, ẹ ni o wu yin lati lọ siluu oyinbo. Njẹ adura naa dẹ ti gba bayii?

Madam No Network: A dupẹ lọwọ Ọlọrun o. Eletiigbaroye ni, mo ti si lọ Dubai, mo ti lọ si Canada, mo ti lọ si London lẹẹmeji, ninu ọdun ta a tiẹ wa yii, mo ti lọ si London, mo ti lọ si Uganda, mo ti lọ si Kenya, mo tun n mura omi-in lọwọ bayii, kiku ma pa wa, ko dẹ ma pa awọn ololufẹ mi, ko ma pa awọn alaaanu mi patapata.

ALAROYE: Bawo lo ṣe ri lara yin lọjọ tẹ ẹ kọkọ fẹsẹ tẹ
ilu oyinbo?

Madam No Network: Mi o tiẹ ti i tẹ ilu oyinbo gan-an, nigba ti ẹronpileeni ti gbera, mo kan wo o pe haaa, irọ ni, irọ ni, ti mo fi wọle, ti baaluu yẹn gbera bayii, to gbe ẹnu soke, omi lo bọ loju mi pe ileri Ọlọrun pada ṣẹ ninu aye mi.

ALAROYE: Nigba tẹ ẹ dọhun-un, bawo ni iṣesi, ihuwasi ati igbesi aye aṣa wọn lọhun-un, bawo dẹ ni ọrọ nẹtiwọọki lọhun-un naa dẹ ṣe ri?

Madam No Network: A dupẹ lọwọ Ọlọrun. O daa, ṣugbọn sibẹsibẹ naa, ọmọ ẹni o ni i ṣe idi bẹbẹrẹ, ka ko ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomi-in. Ilu wa naa niluu wa aa maa jẹ, ilu tiwọn naa niluu wọn aa maa jẹ. Ki Ọlọrun ba wa tun ilu tiwa naa ṣe ko daa.

ALAROYE: Ṣe wọn mọ yin si Madam No Network lọhun-un yẹn naa?

Madam No Network: Wọn mọ ọn o. Ko si ilu ta a de ti wọn o mọ network yẹn o. Wọn mọ ọn.

ALAROYE: Iyẹn ni pe network n lọ lọhun-un yẹn naa?

Madam No Network: Awọn ololufẹ mi n jẹ ki n mọ pe awọn tẹle mi, awọn n ṣe temi gidi gan-an. Gbogbo ilu ti mo de ni wọn ti jẹ ki n mọ pe awọn n gba temi.

ALAROYE: Ere tiata tẹ ẹ n ṣe yii, njẹ ẹ mu iṣẹ mi-in mọ ọn?

Madam No Network: Hmmm, mo maa n ṣe adari eto lode ariya (MC), alaga ijokoo ati alaga iduro. Bẹẹ ni mo tun n ṣe aṣoju fawọn ileeṣẹ nla.

ALAROYE: Awọn aṣeyọri wo lẹ ti ṣe nidii iṣẹ yii?

Madam No Network: O pọ, ki Ọlọrun ṣaanu fun wa naa ni. A n lo mọto, ki Ọlọrun kọle ayọ fun wa. A o ti i kọle o, amọ ki Ọlọrun kọle ayọ fun wa. Ninu ẹ naa la dẹ ti lọ siluu oyinbo. ALAROYE: e ipa ẹyọ kan ṣoṣo ti wọn mọ yin mọ lẹ le ṣe abi ti wọn ba pe yin kẹ ẹ kopa mi-in ninu ere ẹ le ṣe e?

Madam No Network: Ṣe ẹ ri eyi tẹ ẹ beere yẹn, lọwọlọwọ bayii, ibi ti aye ba yi si la maa ba wọn yi si o. Ṣe ẹ ri lọwọlọwọ bayii, no network yẹn laye fẹẹ gbọ, oun ni wọn fẹẹ ri, ti wọn fẹẹ wo. Idi ti mo fi sọ bẹẹ ni pe, mo ti ṣe rẹkọọdu nigba kan to jẹ pe mo kan ṣe e ki wọn mọ pe ki i ṣe no nẹtiwọọki yẹn nikan ni mo le ṣe. Lawọn ololufẹ mi ba bẹrẹ si i pe mi pe, ohun ti mo ṣe jọ awọn loju gan-an o, emi doju ti awọn, mo ja awọn kulẹ, wọn ni ṣe ẹni to diti maa n la eti pada ni. Ṣe ẹ mọ gbogbo iru nnkan bẹẹ yẹn. Wọn kan ṣaa ba mi fi ifẹ ra kasẹẹti yẹn, ṣugbọn wọn jẹ ki n mọ pe awọn o ko nnkan yẹn jẹ. Koda gan-an, awọn mi-in maa n sọ pe mama no network o, ẹ ba wa ṣe fidio kekere fun ọjọ ibi wa, ti n ba ṣe e fun wọn, wọn aa lawọn o fẹ, no nẹtiwọọki yẹn gangan ni ki n fi ṣe e. Lọwọlọwọ bayii o, bi wọn ṣe fẹ ẹ niyẹn, a dẹ ṣi n t ọna yẹn lọwọ, ki Ọlọrun ma jẹ ko bajẹ.

ALAROYE: Awọn ipenija wo lẹ ti ba pade lẹnu iṣẹ yii to ti fẹ mu ko yọ lọkan yin?

Madam No Network: Aimọye. Igba kan, a n ya fiimu kan lọwọ nisinyii, ‘Akọ Okuta’ ni, awa la ni in, Ijẹbu-Ode la ti lọọ ya a, mo ni ijamba ọkọ kan nigba yẹn to lagbara gan-an to jẹ pe ori ni mo mu lọ silẹ. Emi ati ọrẹ mi Tawa, mo dẹ fẹẹ lọọ wa ọsibitu ta a maa lo ni ni mo fi sare lọ.
Aimọye bẹẹ bẹẹ, ọjọ mi-in a le lọ ka ma jẹun, bii ka sun ita lọjọ mi-in. Wọn o ni i fun ẹ lounjẹ nitori iwọ lo lọ sibẹ ki wọn le ri ẹ, ko sohun to o fẹẹ ṣe ju ko o tọju ara ẹ lọ. Awọn ẹbi mi ni ki n fi iṣẹ yẹn silẹ o. Wọn ni mo n fiya jẹ ara ẹ mi ni. Mo ni ibi teeyan ba ti ṣubu, teeyan ba tẹ iṣan mọ ibẹ, o le dide. Ohun ti ko jẹ ki n sọ pe mo fẹẹ jawọ nibẹ niyẹn, aimọye afojuri ati adojukọ. Lara ẹ ni iru ijamba mọto ta a ni laipẹ yii, emi atawọn alabaaṣiṣẹpọ mi, ibi iṣẹ la ti n bọ to fi ṣẹlẹ. Ọlọrun yọ awọn, tori bi bireeki tirela yẹn ṣe sọnu bayii, to fẹẹ lọ sọdọ wọn loun jawọ pada. Jija to jawọ pada bayii, o ba tirela mi-in to n bọ ni, o waa fori sọ ọdọ tiwa, o fẹẹ gori mọto yẹn ni, ọpẹlọpẹ Ọlọrun. Mo dẹ tun dupẹ lọwọ awọn ololufẹ mi naa ti wọn n pe mi, mo dupẹ lọwọ gbogbo wọn. Aimọye nnkan teeyan n ri. Bẹẹ naa ni ọrọ iṣẹ ṣe ri, ẹ mọ pe ẹni to ba ri funfun, o maa ri dudu diẹ, ki Ọlọrun ma jẹ ki dudu pọ ju funfun lọ ninu aye wa ni. Emi ti mo lọ siluu oyinbo, ṣebi lara igbadun iṣẹ yii naa ni, nigba ti ti ijamba mọto yẹn naa dẹ tun de, Ọlọrun tun fẹẹ dan igbagbọ mi wo ni, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko si nnkan to ṣe awọn ọmọ, ko dẹ sohun to ṣe mi. Mọto nikan lo bajẹ, Ọlọrun aa dẹ tun un ṣe.

ALAROYE: Iha wo lawọn obi yin kọ si iṣẹ tiata tẹ ẹ yan laayo yii?

Madam No Network: Dadi mi o mọ nipa gbogbo nnkan bẹẹ yẹn tori aafaa ni wọn. Ko kan wọn, amọ mama mi n sọ pe awọn o fẹ o, tori igbagbọ wọn ni pe oogun pọ nitori ba a ṣe maa n ṣere ori itage nigba yẹn. Mama mi a maa sọ pe awọn ko fẹ ki n di oṣere, nitori wọn maa n ṣoogun ni o. Ẹgbọn mi kan lo ti kọkọ n ṣe e tẹlẹ, mo ti gbagbe orukọ ti wọn n jẹ lori siteeji. Igba ti wọn waa dele ti wọn n kọrin ti wọn maa n kọ lori itage nigba yẹn, awọn orin bii: ‘Wẹrẹwẹrẹ ni ina n jo o, bo ba r’epo a bu lala’. Ẹ mọ pe iru awọn orin ti wọn n kọ wa nigba yẹn niyẹn.
mọmi mi wa n ba wọn wi lọjọ kan, wọn waa yọ ẹgba pe awọn fẹẹ na an, oun kan yi orin tiata wẹrẹwẹrẹ yẹn wọ ọ ni. Ni mọmi mi ba ni, ẹẹn ẹẹn, o n pọfọ fun mi abi, nitori pe o ti n ṣe tiata, ‘omi lo n pa oro ina’. Lo ba loun o ni i lọ sibi tiata yẹn mọ. Amọ igba ti emi fi maa bẹrẹ temi, wọn o fi bẹẹ sọrọ mọ, amọ wọn o jẹ ki ẹgbọn mi yẹn ṣe e. Ọlọrun kan ṣaa ti sọ pe ogo kan fẹẹ jade latinu idile yẹn lo jẹ ki emi maa ṣe e lọ. Gbogbo igba to fi wa n daa nisinyii, awọn mejeeji ti ku, ki Ọlọrun fọrun kẹ wọn.

ALAROYE: Ọjọ wo ni inu yin dun julọ nidii iṣẹ yii?

Madam No Network: Ọjọ ti inu mi dun pọ. Amọ ọjọ ti inu mi kọkọ dun ni igba ti ‘Saburi’ jade. ‘Daginni daginni bọda ọdẹ, bọda ọdẹ’. Ko pẹ ti mo ṣe ‘Lagos to Benin’, ‘Daginni Daginni’ yẹn lo tẹle fiimu yẹn. Nigba ti mo waa lọ si Ilọrin, kasẹẹti yẹn n ta lọwọ nigba naa, awọn ero waa pọ, ọrẹ mi ti mo sin lọ gan-an ko tete mọ, wọn waa bẹrẹ si i pọn gbogbo oke ile wọn, wọn wa n pariwo,  ‘Iya Saburi, Iya Saburi, a fẹẹ ri iya Saburi. Wọn waa bẹrẹ si i na wọn. Mo waa bọ si faranda ile wọn, mo waa ri ero, wọn ti pọn Oke ile yẹn, wọn to mọ gbogbo ile yẹn. Mo waa ni ẹ ma na wọn, emi ni wọn wa wa. Mo wa wo o pe emi naa? Omi kan bẹrẹ si ni ja bọ loju mi ni. Ọjọ yẹn ni mo kọkọ ri i pe inu mi dun, tori wọn tẹwọ gba mi, latigba yẹn naa lawọn ololufẹ mi dẹ ti n gba mi tọwọtẹsẹ.

ALAROYE: Ẹ o fi bẹẹ kawe pupọ. Nibo lẹ duro si ni ti ọrọ ileewe de?

Madam No Network: Haaa, ṣe ẹ ri ti ọrọ onileewe de yẹn, ki Ọlọrun ṣaanu wa ni o, Ọlọrun kọ wa mọ ọn ṣe. Tori bi mo ṣe mọ ọn diẹdiẹ gan-an o ye mi. Emi o kawe, mo dẹ tun ka, tori dadi mi kawe, ṣugbọn arugbo ara ni wọn fi bi mi. Awọn eeyan dẹ gba mi lọwọ wọn lati tọ mi. Ẹ dẹ mọ ọrọ awọn eeyan, wọn o ni i ṣe ẹ bii pe awọn lawọn bi ẹ, nitori naa nkọ, iṣẹ, iṣẹ, iṣẹ ile lo maa n pọ ju iwe yẹn lọ nigba yẹn. Iṣẹ ile yẹn ni wọn dẹ fi kọ mi ju pe keeyan lọ si ileewe, o dẹ mọ mi lara di isinyii naa.

ALAROYE: Ṣe aikawe yẹn o mu kawọn eeyan maa
lo ọgbọn iwe fi fẹ rẹ yin jẹ?

Madam No Network: Ọlọrun n gbeja emi naa ni gbogbo ibi. Ko faaye silẹ lati jẹ ki awọn eeyan rẹ mi jẹ. Mi o sọ pe wọn o le rẹ mi jẹ nibi iwe o, amọ Ọlọrun o waa fi aaye yẹn silẹ. Ọlọrun jẹ ki n mọ ọn kọ mọ ọn ka diẹ. To o ba kawe ju mi lọ rẹpẹtẹ, o le sọ oyinbo nla, emi le sọ ọ ko ma to tiẹ, amọ maa ṣaa ṣi sọ diẹ nibẹ. Pẹlu ẹ naa, Ọlọrun dẹ n ba wa ṣe e, awọn ti wọn n pe wa lati waa ṣe aṣoju ileeṣẹ wọn, wọn o jẹ ki aaye yẹn yọ silẹ ju. Ọlọrun dẹ ṣe e, mo ti ni manija to n ba emi naa ṣiṣẹ.

ALAROYE: Bo ṣe jẹ ipa alawada lawọn eeyan mọ yin mọ tẹ ẹ n ko ninu ere yii, akoba wo lo ti ṣe fun yin?

Madam No Network: Nnkan to kan ṣẹlẹ ni pe ti mo ba de ọja ti mo fẹẹ ra nnkan nigba mi-in, boya mo ti ni in lọkan pe mo fẹẹ ra nnkan pupọ. Bi wọn ṣe maa maa fa mi, ti wọn a maa na mi, gba mi, ko ni i le jẹ ki n ra nnkan ti mo fẹẹ lọọ ra lọja yẹn gangan. Ti n ba tun waa fẹẹ ra awọn nnkan mi-in nigba mi-in gan, ti wọn ba ni tiri Naira lawọn n ta a, ti mo ba ni tuu Naira, wọn aa ni ṣe o yẹ ki emi maa naja, emi to jẹ pe no network ni mi. Gbogbo iru awọn nnkan bẹẹ yẹn naa lo n ṣẹlẹ. Ko dẹ si ọgbọn pe ko ma ṣẹlẹ, nitori ọmọ ti aye ba fẹ, laye n gbe jo.

ALAROYE: Laipẹ yii
la ri ẹyin onitiata lẹyin awọn oloṣelu nigba ti wọn ṣe iwọde fun ọkan ninu awọn to n dupo aarẹ ni Eko, bawo lo si ṣe ri lara yin?

Madam No Network: Awọn mi-in pe mi, awọn eeyan dẹ n sọ oriṣiiriṣii ọrọ, wọn n sọ pe, ‘no nẹtiwọọki, ṣe o yẹ ki ẹ ba wọn ṣe rali yẹn, ṣugbọn ohun ti mo kan fi n fun wọn lesi ni pe ẹnikẹni to ba maa tun Naijiria ṣe ti Naijiria ba maa daa lemi n tẹle o. Ko baa jẹ ọdọ tabi agbalagba, ko baa si jẹ ọmọde, ki Naijiria yii ṣaa ti da bii ilu oyinbo ta a n lọ yẹn, ta a lọọ n kowo wa nibẹ, kawọn ọmọ wa naa riṣẹ ṣe, kawọn naa maa rowo. Nnkan temi fẹ niyẹn, emi o ba ẹnikankan ja o. Ẹni to ba maa tun ilu ṣe lemi n ba ṣe o.
Ki i ṣe pe mi o jade, loootọ ni mo jade fun iwọde yẹn, ṣugbọn ibi to ba ṣaa maa daa naa ni.



ALAROYE: Awọn eeyan sọ pe owo ni wọn n gbe fun ẹyin onitiata kẹ ẹ le ba wọn ṣe rali?

Madam No Network: Emi o gbowo lọwọ ẹnikẹni o. Ṣugbọn nitori mo ri i pe awọn agbaagba ẹgbẹ wa wa nibẹ ni, ibi taye ba yi si naa la maa ba wọn yi si. Mi o gbowo lọwọ wọn, wọn o dẹ pe mi, amọ nitori pe awọn eeyan wa wa nibẹ. Ati pe nitori ti MC Oluọmọ wa nibẹ, to jẹ pe awọn naa maa n duro ti wa nigba mi-in, o tan o. Oun ni gbogbo wa kan fi lọ, ki i ṣe pe boya nitori owo kan tabi nnkan kan to pa mọ. Wọn o ṣaa ti i bẹrẹ ipolongo ibo ta a ba fi maa ni a ti n tẹle wọn lọ, ṣugbọn nitori ko le daa naa ni gbogbo wa fi n wo o pe a o mọbi ta a le yi si to le daa.

ALAROYE: Ṣe ti awọn oloṣelu mi-in ba tun waa ba yin pe awọn fẹ kẹ ẹ ṣe atilẹyin fun awọn, ṣe ẹ maa lọ?

Madam No Network: A maa bẹ Ọlọrun naa ni pe ẹnikẹni to ba pe mi ti mo ba maa ba ṣiṣẹ, tori emi ki i tẹle olofo latilẹ mi. Mi o ki i ṣe oloṣelu o, koda gan-an tẹ ẹ ba wo o daadaa, emi ki i fi bẹẹ si lori ẹrọ ayelujara, tiata to kan gbe mi saye ni. Mi o ki i ṣe eeyan to fẹran afẹfẹyẹyẹ. Ti wọn ba pe mi, inu yara mi nibi ni mo wa, ti mo ba ri i pe ẹ le ṣe e, ẹyin lẹ maa ṣe e to maa daa. Ma a tẹle iru ẹni bẹẹ o, emi o ba ẹni kan ja o, tori pe mi o lọtaa, mi o dẹ ni ọrẹ, mo n da ṣe temi ni, Ọlọrun lo dẹ n tọ emi sọna. Ki i dẹẹ ṣe pe owo ẹgbẹ oṣelu kan ni mo fi debi ti mo de lonii yii, mi o dẹ gbowo lọwọ eeyan fi ṣe rali. Emi kan fara mi silẹ pe ki n fi ṣe faaji ni temi ni.

ALAROYE: Iha wo lẹ kọ si TAMPAN ati ANTP?

Madam No Network: Nnkan to ṣẹlẹ ni pe ati TAMPAN ati ANTP, ọkan naa ni gbogbo wa. Ọrọ yẹn da bii ọrọ Ọlọrun ni. babalawo n pe Ọlọrun, wolii n pe Ọlọrun, aafaa n pe Ọlọrun, ṣebi Ọlọrun yii kan naa la jọ n pe. Ti TAMPAN ba pe mi lati lọ bawọn ṣiṣẹ, maa lọ bawọn ṣe e, bi ANTP ba pe mi maa lọ. Emi o ba ẹnikẹni ja o, gbogbo wọn ni mo n ba ṣe. Iya gbogbo wọn, iyawo gbogbo wọn lemi o. Ibi towo ba ti maa yọ lemi wa o. Ti wọn ba ti pe mi lori iṣẹ ti mo n ṣe, to jẹ ipa ti mo n ko ni wọn pe mi fun, ko ṣeni ti mi o ki i jẹ ipe rẹ. Mi o ni ikunsinu si eyikeyii awọn ẹgbẹ yẹn.

ALAROYE: Ọpọ awọn oṣere alawada ni wọn ti n dide lẹyin tiyin, ọgbọn wo lẹ n ṣe lati le ri i pe ẹ ṣi n rọwọ mu?

Madam No Network: Ẹ mọ pe nnkan ti Ọlọrun ba n ṣe lọwọlọwọ, ko sẹdaa to le da a duro. Tẹ ẹ ba wo o nita nisinyii, agaga ori ẹrọ alatagba bii YouTube, Instagram, awọn alawada ti wọn n dide bọ maa n pe mi tori pe iru ipa ti mo n ko yatọ si ti gbogbo eeyan, ko wọpọ. Bi wọn dẹ ṣe n pe mi ni mo n da wọn lohun, to o ba ti sanwo mi fun mi. Ti wọn ba pe mi to ba jẹ alawada ni, ti mo ba ni mi o ba ọmọ kekere tabi ọdọ ṣe, ta ni mo waa fẹẹ ba ṣe? Nnkan tawọn ọmọ isinyii n ṣe lori Instagram lawa naa n tọpasẹ ẹ. Nnkan tawọn ọdọ oni yii ba dẹ ti n ṣe teeyan n tẹle e, iru ẹni bẹẹ o ni i dẹni ana. Amọ teeyan ba n wo o pe ọmọ kan kere, mi o le ba wọn ṣe, iyẹn nikan lemi o le sọ. Amọ emi n ba ọmọde ṣe, mo n ba agba ṣe, oun ni mo fi n gbera pẹlu wọn.

ALAROYE: A n gbọ pe Madam no network tun fẹẹ pada si ọdọ Lanko o, ṣe ootọ ni?

Madam No Network: (O rẹrin-in lọ) O daa, ko buru, emi o pada sile Lanko o. Ki i ṣe ọdun kẹwaa ti emi ati Lanko ti kọra wa silẹ ree, wọn ni tobinrin ba daa, ọkunrin o ni kọ ọ silẹ, mi o sọ pe mo fẹẹ fẹ Lanko o, mi o ṣe wẹdin pẹlu ẹ o. O ti ni awọn iyawo tiẹ to ti fẹ, emi naa dẹ ti lọkọ temi, ṣugbọn ti wọn ba pe wa papọ, a jọ n ṣiṣẹ, boya iyẹn ni ko jẹ ko han sawọn eeyan pe a o fẹra wa mọ. A o fẹra wa mọ, mi o si labẹ ẹ, mi o si labẹ orule ẹ gan-an mọ. Mo da duro temi ni, mo dẹ ti lọkọ mi-in. Eyi ti wọn n sọ pe mo fẹẹ ṣeyawo pẹlu Lanko yẹn, irọ lasan ni wọn n gbe kiri o, iyẹn o le sẹlẹ mọ. Mi o waa le sọ boya ti ọkan ninu awọn ọmọ ẹ ba fẹẹ ṣe nnkan o, ijokoo le da wa pọ.

ALAROYE: Ṣe ajọṣe ṣi n wa lori ọrọ awọn ọlọmọde, iyẹn eso ti Ọlọrun fi da yin pọ?

Madam No network: Ẹẹn, tawọn ọmọ ba ni nnkan an ṣe, wọn n lọ sile baba wọn. Ọkan lo n woju mi yii, ti wọn ba ni nnkan an ṣe, ko sija, ko si wahala, a o kan jọ fẹra wa mọ ni, ko si fifẹ laarin wa mọ, gbogbo wa ti di famili.

ALAROYE: Ki lẹ le sọ nipa ọjọ ọla ere yii
, awọn iranlọwọ wo lẹ nilo lọdọ ijọba?

Madam No Network: Ṣe ẹ ri i, iṣẹ tiata n sun siwaju si i ni. To ba ṣe n sun, awa naa a maa sun tẹle e ni. Ko sẹni kan to le sọ pe bayii ni ọla tiata ṣe maa ri ju pe ka sọ fun Ọlọrun ko ba wa tun un ṣe lọ. Tori pe bẹ ẹ ṣe sọ pe gbogbo ẹ ti n laju, awọn nnkan kan wa to jẹ pe a maa n ṣe tẹlẹ ta o ṣe mọ. Ta a ba waa wo o nisinyii, owo ta a fi n gbeṣẹ jade nisinyii ki i ṣe ohun la n ri. Igba kan wa to jẹ awọn kan maa kowo rẹpẹtẹ silẹ lati gbe eeyan jade, ṣugbọn asiko kan de to jẹ pe ti wọn ba kowo yẹn silẹ, wọn ki i rowo gidi lọ titi mọ gẹgẹ bi awọn ti wọn n ṣe ẹda kasẹẹti wa ti wọn n pe ni piracy ṣe wa nita. O maa n jẹ ki ẹlomi-in kuta, o n jẹ kaya awọn eeyan maa ja lati kowo silẹ, ṣugbọn sibẹ naa, awọn eeyan o fẹ ki orisun tiata di nnkan igbagbe. Tẹ ẹ ba waa wo nnkan to n lọ nita nisinyii, agaga awọn ọmọ yẹn, bi wọn ba mu foonu lasan dani lati ṣe fiimu, wọn n pawo o. Ṣe a maa waa duro pe a o ni i tẹle ohun ti wọn n ṣe yẹn ni? Ibi towo ti n yọ naa niyẹn. Fun idi eyi, teeyan ba ti n ṣe fiimu, ko maa ṣe e lori ẹrọ ayelujara, ko maa ja gbogbo ẹ pọ naa la le fi ba bo ṣe n lọ o. Amọ ki Ọlọrun ba wa tun gbogbo ẹ ṣe to jẹ pe awọn to jiya iṣẹ yii, bii iru emi. Emi jẹya tiata daadaa, mo dẹ mọ pe emi maa jẹ ọrọ ẹ daadaa. Ti pe kawọn ti ko ṣe wahala waa maa ko ifa yẹn, oun lemi fẹ ki Ọlọrun ba wa tun ṣe debii pe ko kari awọn ọdọ to n bọ lẹyin ati gbogbo awa ta a ti wa nibẹ ṣiwaju, ki ọkan gbogbo wa balẹ ko le to jẹ fun wa.
Iranlọwọ ti emi kan fẹ kijọba ṣe fun wa ni pe lawọn orilẹ-ede okeere lọhun-un, o maa ni awọn nnkan tawọn ijọba maa n ṣe fawọn irawọ oṣere, kawọn ijọba wa naa dide. A o sọ pe wọn ki i ṣe e o, amọ ko ti i to, ki wọn tubọ ran wa lọwọ paapaa ju lọ, awọn agbaagba aarin wa ti wọn ti darugbo to jẹ pe ko si nnkan kan fun wọn mọ. O maa n jẹ nnkan itiju fun mi nigba mi-in tẹlomi-in ba n ṣaisan, ti wọn waa gbe e sori afẹfẹ pe ki wọn dawo fun un. Ti wọn wa n sọ pe ẹ ba wa dawo fun un, ẹ ṣaanu ẹ. Owo ta a n ri nidii iṣẹ tiata, ko to wahala ta a n ṣe lori ẹ, ṣugbọn sibẹ naa, t’Ọlọrun ba fi alubarika sidii iṣẹ eeyan, oni piọwọta aa kọle o. Kawa naa ta a jẹ irawọ oṣere naa si mọ iwọn ara wa. Nigba ti iṣẹ to o n ṣe o ba pọ to o fẹyawo bii ogun bii ọgbọn, to o bimọ bii ọgọrun-un, ṣe ijọba lo ran ẹ ni gbogbo iyẹn. Emi ti mi o waa bimọ pupọ, ti mo rọra n fowo mi ṣe temi wẹrẹwẹrẹ. Ṣe ẹ mọ, gbogbo iru awọn nnkan bẹẹ yẹn, ki Ọlọrun ṣaanu wa, ki Ọlọrun dẹ ba wa tọ awọn ọkunrin wa sọna ni. Ki Ọlọrun tọ wọn sọna nitori pe kowo tabi orukọ kan ma i ti i de ni, inu otẹẹli ni wọn maa maa gbe, ọjọ alẹ wa nkọ? Nitori naa, tiata too jẹ, teeyan ba mọ iwọnba ara ẹ, to mọ ohun toun ba lọ sibẹ. To o ba ti i lorukọ, obinrin aa pe ẹ, to o ba jẹ obinrin, ọkunrin aa pe ẹ, loriṣiriṣii ni, iwọ ni ko o mọbi to o n lọ. To ba waa jẹ ọkunrin naa, to o ba ti lorukọ bayii, obinrin maa to mọ ẹ, irọ ni wọn n pa o, ogo ara ẹ naa ni wọn fẹẹ gba nibẹ. Nnkan ti mo fẹẹ sọ naa ni pe k’Ọlọrun ba wa tọ awọn eeyan wa sọna, ki Ọlọrun dẹ fi ibẹru si wọn lọkan. Ki ọrọ Ọlọrun maa ho ninu eti wọn. Awọn ijọba wa naa, ki wọn dẹ ran wa lọwọ. Nitori naa, ko sẹni to mọ bi ọla ṣe le ri, Ọlọrun nikan lo mọ bi ọla ṣe maa ri o.

 ALAROYE: Ṣe awọn ọkunrin ṣi n pe yin?

 Madam No Network: Nigba ti ki i ṣe pe mo ja lapa tabi mo ge lẹsẹ, iru ọrọ wo ni olootu n sọ yii?( o rẹrin-in) ọmọ ọdun meloo ni mi tẹ ẹ maa ni ki ọkunrin ma pe mi. Ti wọn ba pe mi, emi ni mo mọ pe mi o ni i ṣe palapala pẹlu wọn. Ẹ lọọ beere lọwọ awọn eeyan, mi o ki i lọ pati tabi kilọọbu, mi o laju de gbogbo ibẹ yẹn. Inu ile mi ni emi pẹlu awọn alabaaṣiṣẹpọ mi ti maa n ṣe faaji wa. Mi o dẹ ki i ṣe oniṣekuṣe obinrin, tọkọ ba dẹ kọ eeyan, ṣebi ọkọ leeyan maa fẹ? Ehn ehn, o ti tan.

 ALAROYE: Njẹ ẹ le kọọyan niṣẹ tiata yii abi ẹ lawọn tẹ ẹ n kọ?

 Madam No Network: Awọn eeyan wa daadaa, awọn ọmọ ẹgbẹ mi wa daadaa. Awọn mi-in fẹẹ kọ ọ, amọ ki i ṣe iru ipa ti mo n ko yẹn ni wọn fẹẹ kọ o. Ẹyin ẹ wo iru Fẹla nisinyii, ẹ wo bo ṣe lorukọ to, ṣe ẹ mọ pe ogo yẹn, oun lo ni in, loootọ awọn ọmọ ẹ n gbiyanju o, amọ ko ba ti Fẹla. Ogo kan lo maa n wa, nigba teeyan ba ṣawari ara ẹ, t’Ọlọrun ba ti wa gbe ẹ jade, pe o n sin eeyan kan jẹ o sọ pe ki ogo ẹ jade. Ẹyin ẹ wo iru Lukuluku nisinyii, aimọye awọn ti wọn ti ṣe Lukuluku kọja. Aimọye bẹẹ bẹẹ bẹẹ. Tawọn naa ba waa ṣawari ara wọn, mo maa n sọ fun wọn pe ẹ ma wo o pe nitori mo ti n ṣe no nẹtiwọọki, dandan dandan no nẹtiwọọki lẹyin naa fẹẹ ṣe. Rara o, boya Ọlọrun ti kọ ọ pe ibi temi fẹẹ gba la, ti mo maa gba jade niyẹn. Ma a ni, wo nnkan gidi mi-in lara mi to o maa ṣe to maa yatọ si temi, tiwọ naa aa le tete rọna lọ. Ki i ṣe dandan keeyan loun fẹẹ maa kopa tẹnikan n ko nitori pe o ti lorukọ.

 ALAROYE: Imọran wo lẹ ni fawọn to fẹẹ gbegba tiata?

 Madam No Network: Nnkan meji ni, awọn ọmọ isinyii o fẹẹ fara gbolẹ fun ọga kankan mọ. Ẹlomi-in aa tilẹ pe mi, wọn aa ni, ‘No Network, mo fẹẹ dara pọ mọ ẹgbẹ tiata yin, eelo lẹ maa maa fun mi loṣooṣu?’ Ma a ni ṣe mo raja lọwọ ẹ ni, o o ṣe duro sile yin. Wa a kọṣẹ ni, awa kọ ọ ni, emi kọṣẹ tiata, mo ṣe firidọọmu nidii ẹ. Iwe-ẹri ti mo gba lọwọ ọga to kọ mi niṣẹ wa nibi paapaa. O kere tan, wa a tiẹ kọ ọ fọdun kan tabi ọdun meji ti wa a fi mọ ọn, tiwọ naa aa fi le sọ pe ọga mi niyi. Amọ awọn ọmọ isinyii o fẹẹ kọ ọ, wọn o fẹẹ mọ, amọ irọ naa ni, aaye ẹ maa n yọ silẹ nigba mi-in to jẹ pe pupọ ninu awọn ti wọn n ṣe e lori ẹrọ ayelujara yẹn aa tun pe wa pe ka a maa bọ, ka a waa ti awọn lẹyin. Ko si bo ṣe fẹẹ ri, aaye ẹ maa yọ silẹ, wọn o le da a ṣe. Nitori awọn ọmọ isinyii gbọdọ ni suuru, ki wọn si lẹmii ifarada tori wọn o fẹẹ fara gbolẹ fẹnikẹni, nigba ti foonu tiẹ ti waa de nisinyii, ti wọn ba ti ki i mọlẹ bayii, wọn ti di irawọ loju ara wọn niyẹn. T’Ọlọrun ba tun waa ba wọn ṣe e ti wọn lawọn to n tẹle wọn lori ẹrọ ayelujara to ti pọ, ti wọn tun wa n ri ṣenji diẹ diẹ, haaa igara ti bẹrẹ. Ṣugbọn Ọlọrun o jẹ kiru awa yii di ẹni yẹpẹrẹ, ki Ọlọrun ma yẹpẹrẹ wa o ati gbogbo awọn ololufẹ mi patapata, ki Ọlọrun dẹ jẹ kawọn naa maa tẹsiwaju, ko kọ wọn mọ ọn ṣe.

Leave a Reply