Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan bii ọgọrin larun iba Lasa ti ṣeku pa laarin ọdun kan soso nipinlẹ Ondo.
Adele Kọmisanna feto ilera, Dokita Jibayọ Adeyẹye, lo fidi ọrọ naa mulẹ nibi eto ilanilọyẹ kan lori arun iba Lasa niluu Ọwọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
O ni iye awọn eeyan ipinlẹ Ondo ti arun Lasa ti ran sọrun ọsan gangan laarin ọdun 2020 nikan ju iye awọn ti arun korona pa lọ.
Ninu awọn ipinlẹ mẹta ti arun Lasa ti gbilẹ ju lọ lorilẹ-ede yii, ipinlẹ Ondo ni kinni ọhun ti paayan ju pẹlu bi o ṣe ko ida mẹrindinlogoji ninu marundinlọgọrin.
Kọmisanna ọhun ni eeyan mọkanlelogoji pere lo ba iṣẹlẹ arun korona lọ nipinlẹ Ondo, nigba tawọn to ti ku nipasẹ arun iba Lasa le lọgọrin daadaa.
O ni ọjọ pẹ ti arun yii ti n sọsẹ, ti ko si figba kan kuro nilẹ, bo tilẹ jẹ pe asiko ẹẹrun ta a fẹẹ wọ yii lo maa n wọpọ ju laarin awọn eeyan.
Ijọba ibilẹ Ọwọ ati Ọsẹ lo ni ajakalẹ arun yii ti wọpọ ju, to si n kọlu awọn tọjọ ori wọn ko ti i ju mọkanlelogun si ọgbọn lọ.
O ni ijọba ti n pin oogun pekupeku fawọn eeyan ipinlẹ Ondo lọfẹẹ, o rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu akitiyan ijọba lori ati dena iba aṣekupani naa.