Ibalopọ di wahala laarin baba ọgọrin ọdun atiyawo ẹ n’Ibadan, o lobinrin naa ko foun ni ‘kinni’ ṣe daadaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bíi igba ti awọn eeyan naa n ṣere ori itage fawọn ero kootu lo ri nigba ti tọkọ-tiyawo arúgbó kan wọ ara wọn lọ sí kootu nitori Ibalopọ.

Baba ẹni ọgọrin (80) ọdun naa, Alhaji Muritala Haroon, lo fẹsun kan iyawo ẹ, Alhaja Afusat Haroon, o ni ìyá ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin (71) naa n fi iya ibalopọ jẹ oun.

Ṣugbọn iya àgbà yii sọ pe niṣe loun máa n mọ-ọn-mọ kọ̀ fún bàbá agba lati máa bá òun laṣepọ nitori baba naa ti fẹran ibalopọ jù, paapaa nitori pe o ti ko àrùn lara ọkan ninu awọn àlè rẹ̀ to n pe niyawo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Oríṣìíríṣìí obinrin ló máa n gbe wale to máa n pe niyawo oun. Nibi ti oun ati ọkan ninu wọn ti n ba ara wọn sun ninu ile lobinrin yẹn ti pariwo pe ki n waa wo Alhaji, oun ko mọ ohun to ṣe n ṣe wọn o. Bi mo ṣe sáré lọ síbẹ niyẹn lati ṣe aájò wọn.

“Nigba ta a gbe wọn dé ọsibitu ni dokita kọ oogun kan fún wọn, o ni titi ti wọn yóò fi kú ní wọn gbọdọ maa lóògùn ọ̀hún déédé.

“Ko ma lọọ di pe yoo ko tiẹ ba oluwa rẹ̀ ni mi o ṣe gba fún un lati sun mọ mi mọ. Ati pe ki tiẹ loluwa  rẹ gan-na tun fẹẹ fi gbogbo ìyẹn ṣe mọ niru asiko yii, awa ti akọbi wa ti to ẹni ọdun mọkanlelaaadọta (51), ti oun paapaa ko ni i pẹẹ ni ọmọọmọ.

Ṣaaju lolùpẹ̀jọ́ ti ṣàpèjúwe iyawo ẹ gẹgẹ bíi ọdaju eeyan pẹlu bo se gbiyanju lati gbẹmi oun lọjọ kan.

“O ni gbogbo igba ti mo ba ti wọ yara ẹ lati ba a laṣepọ lo máa n fi ilẹkun taari mi danu, tí yóò si le mi pada bọ sita.

“Nigba ti mo fẹyawo le e lo wáá bẹrẹ sí í jowu. Lọjọ kan lo mu ọbẹ waa ka mi mọ inu yara, to fẹẹ fi gun mi.

“Iyawo kekere to ri ọbẹ yẹn lọwọ ẹ lo pariwo to jẹ kí n mọ pé o n bọ waa gun mi lọbẹ. Ti ki i baa ṣe pé mo yẹ ọbẹ yẹn, ti mo sì kó o lọwọ mejeeji sẹyin ni, ọjọ naa ni iba ti pa mi.

“O ti kọyin àwọn ọmọ si mi. Lọjọ kan loun atawọn ọmọ waa fi tipatipa gba iwe ilẹ ilẹ ti mo kọ lọwọ mi. Oun atawọn ọmọ yẹn fẹẹ pa mi ki wọn lè jogún gbogbo dukia mi ni.”

Baba ẹni ọgọrin ọdún naa waa rọ ile-ẹjọ lati fopin sí igbeyawo ọlọdun mejilelaaadọta (52) naa.

Ṣugbọn olùjẹ́jọ́, ẹni tó sọ pé òun ko gbiyanju lati gùn oko oun lọbẹ ri, ta kò ọkọ e pé òun ko fara mọ ìpinnu náà nítorí òun ti fi gbogbo ìgbésí ayé òun sìn Alhaaji, kò wáá yẹ kó jẹ igba ti oun ti di arúgbó yii ni yóò deede fọn ẹru oun da sita.

Labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, igbimọ awọn adajọ kootu Ọja’ba, to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, ti gba awọn arúgbó mejeeji naa niyanju lati gba alaafia laaye. Lẹyin naa ni wọn sun igbẹjọ naa siwaju lati jẹ ki wọn le yanju ọrọ naa laarin ara wọn dipo kikọ ti wọn fẹẹ kọra wọn sílẹ̀.

Leave a Reply