Ibalopọ lo dija silẹ, l’Ọdunayọ ba fibinu gun ọkọ ẹ pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gba fun mi, n ko gba fun ọ, yunkẹ yunkẹ ti ọkunrin kan fẹẹ bayawo rẹ, Ọdunayọ Olumale, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ṣe lẹyin oṣu mẹta ti wọn ti jọ ṣe e gbẹyin, ṣugbọn ti iyẹn ni oun ko ṣe ti fa iku aitọjọ fun baale ile kan, Ọlamilekan Salaideen, ẹni ọdun mẹtadinlogoju ti wọn n gbe lagbegbe Oko Ọba, niluu Ọyọ Alaafin lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe awọn tọkọ-tiyawo naa ti figba kan ni gbolohun asọ laarin ara wọn, eyi to mu ki iyawo naa ko jade nile lati bii oṣu mẹta sẹyin. O jọ pe lẹyin ti awọn majẹ-o-bajẹ ba wọn da sọrọ naa, ti wọn pari ija to wa laarin wọn fun wọn ni obinrin yii gba lati ko pada sile.

N ni tọkọ-tiyawo yii ba jọ pada sile wọn lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii. Nigba to di alẹ ni ọkọ ba nawọ ifẹ si iyawo rẹ, o ni ko jẹ ki awọn ṣe tibi tibi, ṣugbọn iyawo kọ jalẹ, o ni oun ko ṣe. Gbogbo bo ṣe n gbiyanju lati mu nnkan fun obinrin naa niyẹn n sọ pe oun ko ṣe ṣẹ. Eyi ko dun mọ baale ile naa ninu.

Ṣe wọn ni ko ṣee fi sara ku, o jọ pe ọkunrin naa fẹẹ wọle siyawo rẹ lara tipatipa. Nibi ti wọn si ti n jagudu mọ ara wọn lọwọ, ibinu ọrọ yii ni Ọlamilekan fi fọ foonu iyawo rẹ mọlẹ nigba tiyẹn ko gba fun un.

Ibinu pe ọkọ rẹ fọ foonu rẹ mọlẹ ni Ọdunayọ fi he ọbẹ nilẹ, lo ba gun ọkọ rẹ nibi oke aya rẹ. Ki wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkunrin naa ti gabekuru jẹ lọwọ ẹbọra, o ku patapata.

Baba ọkọ obinrin yii, Ismaila Tijani, lo lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa to wa ni Durbar, niluu Ọyọ, leti lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii ti wọn fi lọọ gbe obionrin naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Oṣifẹsọ, ṣalaye pe ibalopọ lo da wahala silẹ laarin tọkọ-taya naa, ti ọkọ si fibinu fọ foonu iyawo. Niyawo naa ba gun un lọbẹ, ti ọkunrin naa si gbabẹ ku.

O ni Ọdunayọ ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa ni Durbar, niluu Ọyọ. Lẹyin iwadii lo ni wọn yoo gbe e lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply