Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe agbalagba ni wọn, ti ko si eyi to ṣanku ninu wọn, sibẹ, ki i wuuyan ki arugbo ẹni lọ bẹẹ, ka ma ti i sọ ọba to n dari ilu. Eyi lo fa ojo ibanikẹdun to n rọ nipinlẹ Ogun lasiko yii, ti kaluku n ba awọn ọmọ ipinlẹ naa daro awọn ọba nla mẹta to waja nibẹ laarin ọsẹ kan ṣoṣo.
Alakija Ikija, Ọba Shamsideen Ayọrinde lo kọkọ ju awa silẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹrin, oṣu keje yii, ẹni ọdun mejidinlaaadọrun(88) ni kabiyesi naa lasiko tiku de.
Ẹgba Oke-Ọna ni Ikija, Ọba to doloogbe yii si ni ọba akọkọ to jẹ Alakija. Alafẹ ọba to mọ nipa okoowo ni. Ọjọ keji ti i ṣe Sannde ni wọn sinku Alakija nilana ẹsin Musulumi.
Afi bo ṣe tun jẹ ọjọ keji ti wọn sinku Alakija ni Ọba Mufutau Akindele, Olu Oke-Odo Ilupeju naa tun waja.
Ọrẹ timọtimọ ni Alakija ati Olu Oke-Odo Ilupeju, iku awọn mejeeji to jẹ tẹle-n-tẹle yii si mu ijọloju dani gidi. Ẹni aadọrun-un ọdun (90), ni Ọba Akindele.
Iku ọba keji yii lawọn eeyan n ba awọn ara ipinlẹ Ogun daro lọwọ ti iroyin iku Olu Imaṣayi, Ọba Gbadebọ Oluṣọla Oni, naa fi bẹrẹ si i ru jade bii eefin l’Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an, oṣu keje.
Wọn ko tete kede ipapoda Olu Imaṣayi laafin, ẹrọ Fesibuuku lo ṣofofo, nitori awọn to mọ bo ṣe n lọ laafin ọba naa ti n dọgbọn gbe e sibẹ.
Nigba to di ọjọ Ẹti ni ijọba ipinlẹ Ogun kede ipapoda Olu Imaṣayi, Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, lo kede ipapoda ọba naa ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti yii.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77)ni Olu Imaṣayi, ọgbọn ọdun to ti wa nipo ọba niku de yii, nitori ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa ọdun 1990 lo ti gori aleefa naa. Ọdun 2005 ni ijọba sọ ọ di ọba onipo kin-in-ni, kabiyesi yii si fi asiko kan jẹ olori awọn ọba Yewa gbogbo, ko too di pe Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenla gori aleefa, to si di olori ọba Yewa.
Ijọba ipinlẹ Ogun, awọn eekan kaakiri awọn ipinlẹ atawọn araalu ni wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun saafin awọn ọba yii, awọn to si le ṣabẹwo sibẹ naa ṣi n lọ sibẹ lati ki awọn eeyan wọn ku aṣẹyinde.