Monisọla Saka
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori iku gbigbona ati ọna ọdaju ti wọn fi pa awọn olujọsin ileejọsin St. Francis Catholic Church, agbegbe Owa-luwa, Ọwọ, nipinlẹ Ondo, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Nigba to n bẹnu atẹ lu iwa laabi ọhun, Buhari ni ibanujẹ ayeraye n duro de awọn ti wọn ṣeku pa awọn eeyan yii laye ati lọrun.
Ninu atẹjade kan ti Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, fi lede ni Buhari ti ni, “Awọn eeyan ibi lati inu iho ilẹ abi lati inu aginju nikan ni wọn le ṣe nnkan aburu bẹẹ, ibanujẹ ti ko lopin lo n duro de wọn laye ati lọrun bakan naa”.
Buhari ṣedaro awọn to ti lọ, bẹẹ lo ba awọn ẹbi, ara, ijọ Katoliiki ati ijọba ipinlẹ Ondo kẹdun awọn ẹni wọn, o wa ke pe awọn ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lati bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-sọka, ki awọn agbofinro si ri i pe ọwọ ba awọn eniyan ibi ọhun, lati le rẹ awọn tọfọ ṣẹ lẹkun.
Buhari tẹsiwaju pe ko si bo ti le wu ko ri, orilẹ-ede yii o ni i gba awọn ẹni ibi ati ika ọdaju laaye, bẹẹ ni okunkun ko ni i bori imọlẹ laelae. Ilẹ Naijiria yoo pada bori ni”.