Ibẹrẹ ọtun ni iyansipo Olu Warri tuntun jẹ ninu itan awọn eeyan Itsekiri- Ọọni Ifẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Arole Oduduwa, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ojaja 11, ti ba awọn eeyan ilu Itsekiri nile-loko kẹdun iku ọba wọn, HRM Ogiame Ikenwoli, to waja laipẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita ni Ọọni ti gbadura pe ki Ọlọrun tẹ kabiesi naa safẹfẹ rere.

Ọba Ogunwusi ṣapejuwe Ikenwoli gẹgẹ bii ọba to ni erongba rere fun awọn eeyan rẹ, to si jẹ ọkan lara awọn ogbontagiri ninu iran Oduduwa, ẹni to tubọ jẹ ki ibaṣepọ to dan mọnran wa laarin ilẹ Itsekiri ati ilẹ Yoruba laarin ọdun marun-un to lo gẹgẹ bii Olu ilẹ Warrri.

O ni ẹni ti gbogbo eeyan maa n bu ọla fun ninu igbimọ agbarijọpọ awọn ọba lorileede Naijiria, National Council of Traditional Rulers of Nigeria, ni, o si jẹ ẹni to maa n gbe igbesẹ iṣọkan ati ifẹ laarin iran Oduduwa ni gbogbo igba.

Ọba Ogunwusi waa gbadura pe ki Olodumare wa pẹlu mọlẹbi ti kabiesi fi silẹ, ko si tu wọn ninu.

Bakan naa ni Ọọni gboṣuba fun gbogbo awọn ọmọ Itsekiri fun bi wọn ko ṣe yẹsẹ ninu ilana ati aṣa ibilẹ wọn lasiko ti wọn yan Ọmọọba Utieyiboritsetsola Emiko, ọmọ ọdun mẹtadinlogoji gẹgẹ bii Olu ti Warri.

O ni ibẹrẹ ọtun ni iyansipo Olu Warri tuntun naa jẹ ninu itan awọn eeyan Itsekiri.

Ọba Ogunwusi ba Ọmọọba Emiko yọ fun iyansipo naa, o ni igbagbọ oun ni pe ibaṣepọ to dan mọnran yoo tun wa laarin iran Oduduwa lasiko rẹ.

Ọọni rọ ọ lati mu ohun gbogbo ti yoo tubọ mu ki alaafia ati idagbasoke wa nilẹ naa lọkunkundun, ki ohun gbogbo si maa lọ deede lasiko tirẹ.

Olu ti Warri to jẹ laarin ọdun 1987 si 2015 lo bi Ọmọọba Emiko, ọmọọbabinrin lati Ogere-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, Olori Duroorike Emiko, si ni iya rẹ.

Leave a Reply