Ibẹru awọn ọlọpaa lo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ileetura Hilton gbe oku Timothy pamọ – Agbẹjọro Adedoyin

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbẹjọro fun Dokita Ramon Adegoke Adedoyin to ni ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, Williams Abiọdun, ti sọ pe nitori ibẹru ohun ti awọn ọlọpaa yoo ṣe ni awọn oṣiṣẹ ileetura naa ṣe gbe oku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy, to ku sibẹ pamọ.

Lọọya Adedoyin ṣalaye yii lasiko to n ba akọroyin The Nation, sọrọ.

Timothy Adegoke lo gba yara nileetura naa lọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii, lẹyin to si di awati lawọn ọlọpaa ko oṣiṣẹ mẹfa nibẹ pẹlu Adedoyin to ni ileetura naa, ko too di pe wọn ri oku Timothy nibi ti wọn sin in si lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu ti a wa yii.

Ṣugbọn ninu awijare Williams, o ni ṣe ni Timothy ti oju-oorun doju iku lalẹ ọjọ to gba yara sileetura naa.

O ni Adedoyin ko mọ pe ẹni to n jẹ orukọ yẹn sun sibẹ nitori ko si akọsilẹ owo to san ninu iwe otẹẹli, idi si niyẹn to fi kọkọ sọ fun awọn ọlọpaa ti wọn lọọ ba a pe oun ko mọ ẹni to n jẹ bẹẹ.

O ni inu akanti oṣiṣẹ kan, Adeṣọla Tobilọla, ni Timothy sanwo yara si, iyẹn si ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe ṣe loun ṣe apapin owo naa pẹlu awọn oṣiṣẹ to ku.

O ni nigba ti wọn ri i pe Timothy ti ku sinu yara, ẹru ba wọn, idi si niyẹn ti wọn fi lọọ ju oku rẹ sinu igbo kan lalẹ loju ọna Ifẹ/Ibadan ti ko jinna pupọ sibi ti otẹẹli naa wa.

O ni Adedoyin tẹ wọn ninu pupọ lati le mọ aṣiri to wa nibẹ, sibẹ, wọn ko jẹwọ titi di igba ti awọn ọlọpaa fi ọwọ lile mu wọn.

Williams fi kun ọrọ rẹ pe wọn ko sinku ọmọkunrin naa, ṣe ni wọn ju u sinu igbo yẹn, ori-oko ẹnikan si ni, awọn agbẹ ti wọn n dako nibẹ ni wọn ri oku yẹn, ti wọn si fi to awọn ọlọpaa leti.

O ni awọn oṣiṣẹ meji pere ni wọn mọ si bi wọn ṣe sin Timothy; Tobilọba ati Kosim ti gbogbo eeyan mọ si Aafaa to n ba wọn tun nnkan ṣe ninu otẹẹli, wọn ko si mu nnkan kan ninu ẹya-ara rẹ.

O sọ siwaju pe Adedoyin ko ran oun lati ba mọlẹbi oloogbe kankan sọrọ tabi fun wọn ni owo abẹtẹlẹ, bẹẹ ni oun ko ti i foju kan mọlẹbi rẹ kankan.

O ni ọlọpaa to n ṣe ẹjọ naa sọ foun pe ara ọkunrin naa ko ya ko too kuro ni Abuja, idi si niyẹn tiyawo rẹ fi n pe e lemọlemọ.

 

Leave a Reply