Ibẹru ba awọn obi lori esi idanwo WAEC ti ko jade l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ibẹru ti ba awọn obi ati akẹkọọ ti wọn ṣe idanwo aṣekagba lọdun yii pẹlu bi ajọ WAEC ko ṣe ti i gbe esi ipinlẹ Ekiti jade.

Ohun to jẹ ki ọrọ naa tun lagbara ni bi iroyin kan ṣe gba igboro pe ijọba Ekiti ko sanwo awọn akẹkọọ fun WAEC, eyi lo jẹ ki wọn gbe esi naa sọwọ. Wọn ni owo ti Gomina Kayọde Fayẹmi maa n san lọdọọdun ni ko ri san fun ajọ naa, eyi lo jẹ ki wọn ṣe nnkan ti wọn ṣe.

Niṣe lawọn obi ati akẹkọọ to lọ sawọn ileewe ijọba kaakiri lati gba esi idanwo naa ba ijakulẹ pade, bẹẹ ni awọn to fẹẹ wo o lori intanẹẹti ko ri i wo, o si jọ pe nnkan ti daru patapata.

Ibẹru yii lo jẹ kawọn tọrọ kan maa bẹ ijọba pe ki wọn ṣaanu awọn nitori esi idanwo yii lawọn akẹkọọ fẹẹ fi ṣeto igbaniwọle si fasiti, ti ohunkohun ba si ṣẹlẹ, adanu nla ni yoo jẹ.

Ṣugbọn ijọba ti ni ko si nnkan to jọ gbese lọrọ awọn, wọn ni Ekiti ko jẹ WAEC lowo kankan, awọn si ti ba ajọ naa sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ.

Kọmiṣanna feto iroyin, Akin Ọmọle, sọ pe akojọpọ awọn esi ọhun ni iṣoro diẹ, awọn si ti kan si WAEC, bẹẹ ni wọn ti tọrọ aforiji. O ni ijọba ko jẹ wọn lowo kankan, ireti si wa pe wọn yoo gbe awọn esi naa jade l’Ọjọbọ, Tọsidee, tabi ọjọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Leave a Reply