Ibi ayẹyẹ iṣọmọlorukọ lawọn eeyan yii ti n bọ ti wọn fi ji mẹta gbe ninu wọn gbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Iroyin to ALAROYE lọwọ bayii fidi rẹ mulẹ pe ibi ikomọ-jade kan ni awọn arinrin-ajo mẹta kan ti n dari bọ lopopona Àbòtó, nijọba ibilẹ Asà, nipinlẹ Kwara, tawọn agbebọn fi ji wọn gbe, bẹẹ ni wọn tun ji fijilante to fẹẹ doola ẹmi won naa gbe.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ Kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, la gbọ pe wọn da awọn arinrin-ajo naa lọna, ti wọn si ko wọn lọ sinu igbo kan lagbegbe Àbòtó.

Alaga ẹgbẹ fijilante ni Kwara, Ọgbẹni Saka Ibrahim, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹfa yii, o ni arakunrin kan lo n komọjade, to si n ko awọn alejo pada sile wọn pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lẹyin ti wọn ṣe ikomọ tan, ṣugbọn awọn agbebọn lọọ da wọn lọna, wọn si ji ọkunrin mẹta gbe lọ ninu wọn. O tẹsiwaju pe fijilante kan ti ko wọṣọ iṣẹ, ti ko si gbe ibọn kankan lọwọ to fẹẹ gba awọn eeyan ọhun silẹ ni wọn tun ji oun naa gbe lọ papọ mọ wọn.

Saka ni gbogbo inu igbo to wa ni agbegbe naa lawọn ti fọ yẹbẹ-yẹbẹ sugbọn awọn ko ri awọn agbebọn ọhun ati awọn ti wọn ji gbe titi di akoko ta a pari iroyin yii. Bakan naa ni wọn ko ti i pe mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe yii lati beere owo itusilẹ lọwọ wọn.

 

Leave a Reply