Ibi ayẹyẹ igbeyawo lawọn kan ti n bọ tawọn agbebọn fi ji marun-un ninu wọn l’Omu-Aran

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni awọn ajinigbe ji awọn arinrin-ajo marun-un gbe lọ ni Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe awọn arinrin-ajo meje ni wọn n dari bọ lati ipinlẹ Ekiti, nibi ti wọn ti lọọ ṣe ayẹyẹ igbeyawo, ọkọ Siẹnna lo n gbe wọn pada si Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ṣugbọn Omu-Aran, lawọn ajinigbe naa to dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro  ti da wọn lọna, ti wọn si n yinbọn soke ko too di pe wọn ji marun-un gbe lọ ninu wọn. Iya arugbo kan ati ọmọ kekere kan ni wọn fi silẹ pe ki wọn maa ba tiwọn lọ, bakan naa ni wọn ko gbe ọkọ ero naa lọ.

Nigba ti ALAROYE, pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, boya wọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa, o ni oun ko ti i gbọ, sugbọn oun yoo ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply