Ibi ibura awọn oloye ẹgbẹ ni wọn ti n bọ tawọn agbebọn fi ji ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹjọ gbe ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ibi ayẹyẹ ibura wọle awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Onitẹsiwaju (APC), ni awọn mejọ kan ti n bọ ti wọn fi ko sọwọ awọn ajinigbe. Marun-un mori bọ, awọn mẹta to ku wa lakata awọn ajinigbe titi asiko ti a n ko iroyin yii jọ.

ALAROYE gbọ pe alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ti wọn pari eto ayẹyẹ ibura wọle fawọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC niluu Ilọrin tan ti wọn n pada si ile wọn ni awọn ajinigbe ji wọn gbe laarin Ararọmi Ọpin si Obbo Ile, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti ji wọn gbe.

Mọlẹbi ọkan lara awọn ti wọn jigbe, Adekunle Oluwọle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe orukọ awọn ti wọn jigbe ni Daniel Adewuyi, alaga Wọọdu Isapa, nijọba ibilẹ Ekiti, adari awọn obinrin ni Eruku, adari awọn obinrin niluu Obbo Ile, alaga wọọdu Obbo Ile, adari awọn obinrin ni Wọọdu Koro ati adari awọn obinrin ni Isapa. Ti wọn si sọ pe eeyan marun-un mori bọ, ti wọn si ti wa nileewosan bayii fun itọju to peye.

Owuyẹ kan sọ pe ogun miliọnu Naira ni awọn awọn ajinigbe naa fẹẹ gba lori ẹnikọọkan awọn adari awọn obinrin mẹtẹẹta to ku lakata wọn.

Nigba ti ALAROYE ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọrọ lori aago, o loun ko ti i gbọ si iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply