Ibi tawọn ajagungbalẹ mẹta yii ti n yinbọn mọ araalu n’Igbẹsa lọlọpaa ti ko wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Loootọ ni wọn n’iku ogun ni i pa akinkanju, ṣugbọn Afaimọ ni ijagungbalẹ tawọn gende mẹta yii, Muyibi Adewale, Kamọru Ayọde ati Taofeek Ogundele, yan laayo ma ran wọn lẹwọn, tori iṣẹ naa ti sọ wọn dero ahamọ ọlọpaa bayii.

Awọn agbofinro lati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Agbara, nipinlẹ Ogun, ni wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, latari ipe tawọn eeyan ilu Igbẹsa fi ṣọwọ si wọn pe ki wọn waa gba awọn lọwọ awọn jagunlabi naa.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi lede, o ni niṣe lawọn mẹtẹẹta tọwọ ba yii, pẹlu awọn janduku kan to kun wọn lọwọ, ṣigun lọọ ba awọn eeyan Abule Jẹgẹdẹ, lẹgbẹẹ ilu Igbẹsa, nipinlẹ Ogun, ni wọn ba bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ, bẹẹ ni wọn n fi ada le tọkunrin tobinrin ilu naa kiri, wọn lawọn fẹẹ gba awọn ilẹ oko kan ti wọn n ṣiṣẹ lori rẹ.
DPO ẹka Agbara, SP Saleh Dahiru, to ko awọn ọlọpaa yooku sodi lọ sibẹ sọ pe niṣe lawọn ọmọ ganfe yii sọ abule naa doju ogun gidi, wọn ti yinbọn mọ eeyan mẹfa, Ọgbẹni Sunday Okorie, Akeem Shonẹyẹ, Lekan Oloyede, Musibau Jimọh, Idris Hamzat ati Akande Oyedeji. Wọn ko ku o, ṣugbọn ọta ibọn ti ṣe wọn leṣe gidi.

Kia lawọn ọlọpaa sare gbe wọn lọ sileewosan ijọba lati doola ẹmi wọn, iyẹn lẹyin tọwọ ti ba awọn afurasi ọdaran naa tan.

Lara nnkan ija oloro ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹfa, ati katiriiji ọta ibọn ti wọn ti yin mẹrinla.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn afurasi ọdaran naa si ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, awọn mẹtẹẹta si ti n gbatẹgun l’Eleweeran, l’Abẹokuta.

O tun paṣẹ pe awari tobinrin n wa nnkan ọbẹ ni ki wọn fi ọrọ awọn ẹgbẹ wọn to sa lọ ṣe, ki wọn tọpasẹ wọn debikibi ti wọn ba sa si.

Biṣẹ iwadii ba ti pari, ilẹ-ẹjọ lọrọ ku si, ibẹ ni wọn yoo ti gba sẹria to tọ si wọn loju paali.

Leave a Reply