Ibi tawọn eleyii ti n jale loju titi lọjọ ọdun tuntun lọlọpaa ti ko wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ohun meremere to daa lọpọ eeyan n gbero ẹ lọdun tuntun, ṣugbọn ni ti awọn mẹsan-an tẹ ẹ n wo yii, bi wọn ṣe maa rowo na lọnakọna lo gba ọkan wọn, ole ni wọn n ja lọwọ loju titi, nibi ti wọn ti n da awọn onimọto lọna lọjọ ọdun tuntun lawọn agbofinro ti mu wọn.

Orukọ awọn afurasi ọdaran naa ni Oluṣeyi Afọlabi, ẹni ọdun mọkandinlogun, Adeyẹmọ Ayọmide, ọmọ ọdun mejidinlogun, Lati Francis, ẹni ọdun mọkandilogun, Rilwan Raji, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Ayọmide Oyediran, toun jẹ ẹni ogun ọdun pere.

Awọn mẹrin to ku ni Rasheed Ibrahim, eni ọdun mejilelogun, Hamzat Abdullahi, ẹni ọdun mọkandinlogun, Musa Gbadamọsi, ẹni ogun ọdun ati Ṣeun Lasisi, toun jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ lawọn ka awọn afurasi naa mọ ikorita Y-Junction, nitosi Too-geeti atijọ, ni Ketu, nipinlẹ Eko.

O lawọn kọlọransi ẹda yii ṣẹṣẹ kọ lu Ọgbẹni Adejare Adetayọ toun atiyawo n kọja lọ lagbegbe ọhun lalẹ ọjọ naa tan ni, wọn gba owo wọn ati foonu, iṣẹlẹ yii lo si fu awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kan to wa nitosi lara, ni wọn ba lepa awọn oniṣẹẹbi naa, Ọlọrun si jẹ ki wọn ri awọn mẹsan-an yii mu, bo tilẹ jẹ pe awọn to ku sa lọ.

Lara nnkan ija ti wọn fi n ṣe ṣuta ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ada meji, ọbẹ aṣooro gigun meji, bileedi atawọn nnkan ija mi-in.

Adejọbi ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko leti, o si ti paṣẹ ki wọn taari awọn tọwọ ba yii si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Eko, to wa ni Panti, ni Yaba, lati tubọ ṣe iwadii nipa wọn.

O lawọn ọlọpaa ṣi n wa awọn to sa lọ, ati pe gbara tiṣẹ iwadii ba ti pari ni wọn yoo foju awọn eleyii ba ile-ẹjọ, ki wọn le gba sẹria to tọ si wọn labẹ ofin.

Leave a Reply