Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo ero to to sileepo kan laduugbo Oluyọle, n’Ibadan, lati ra epo bẹntiroolu niṣẹlẹ ọhun ṣe ni kayeefi pẹlu bi ọkan ninu awọn awakọ to to fun epo naa ṣe deede pa oju de, to si tibẹ kọri sajule ọrun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii.
Bi awọn awakọ yooku ṣe to fun epo lati ra bẹntiroolu nileepo ni baba yii jokoo sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti nọmba rẹ jẹ AKD 878 GP, to n duro digba ti yoo kan oun paapaa lati ra epo sinu mọto rẹ.
Ero to pọ nileepo naa ko jẹ ki kinni ọhun ya, n ni baba ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ, ṣugbọn ti wọn n pe ni Alaaji nitori bi imura rẹ ṣe jọ ti Musulumi yii ba gbori le ori ṣiarin ọkọ rẹ, awọn eeyan si ro pe o n sinmi ni tirẹ ni, ṣe o pẹ diẹ ti wọn ti to sori ila nibẹ nitori wọn ṣẹṣẹ ja epo sileepo naa tan ni.
Ṣugbọn nigba ti awọn ọkọ to wa niwaju bẹrẹ si i sun siwaju diẹdiẹ lẹyin asiko diẹ ti gbogbo wọn ti wa loju kan naa, Alaaji ko sun kuro loju kan naa to wa, awọn to wa lẹyin rẹ bẹrẹ si i fọn fere mọto wọn “pin-in! Pin-n! Pin-in” lati pe e sakiyesi pe aaye ti ṣi silẹ niwaju ẹ, ṣugbọn baba naa ko da wọn lohun.
Gbogbo awọn to n wo baba yii bo ṣe jokoo ti ko mira loju kan naa to wa lọrọ yii bẹrẹ si i bi ninu, to bẹẹ ti awọn kan fi n rọjo eebu le e lori, ti omi-in ninu wọn paapaa si n gbe e ṣepe, ṣugbọn sibẹsibẹ, Alaaji ko kọbi ara si wọn.
Pẹlu ibinu lawọn kan fi sọ kalẹ ninu mọto wọn lati ji baba to gbori le ṣiarin ọkọ ṣugbọn tawọn eeyan ro pe o ti sun lọ yii pe ko sọ oorun yooku digba to ba dele, ko sun mọto rẹ siwaju jare, ọjọ n lọ. Wọn fi ọwọ gba a pẹpẹ, ko tun mira sibẹ, nigba naa ni wọn too mọ pe ki i ṣe pe Alaaji n sun, baba onibaba ti ku patapata ni.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Alamoojuto ileepo naa, Ọgbẹni Joseph sọ pe “Kayeefi nla niṣẹlẹ yẹn jẹ loju mi nitori niṣe ni baba yẹn gbe ori le ṣiarin, to gbẹsẹ ọtun ẹ sori tọtu ninu mọto, to ṣilẹkun ọkọ silẹ, to si fi ẹsẹ keji tilẹ, oorun lasan lawọn eeyan kọkọ ro pe o n sun, laimọ pe o ti ku”.
Alakooso ileepo yii fidi ẹ mulẹ siwaju pe awọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to awon agbofinro leti, wọn si ti gbe oku naa lọ si ibi ti wọn n ṣe oju lọjọ si titi ti wọn yoo fi ri awọn ẹbi ẹ.