Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Aṣaaju apapọ fẹgbẹ oṣelu All People’s Congress, APC, to tun jẹ eekan oloṣelu Eko, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ idi toun fi kọ lati ṣatilẹyin fun Akinwunmi Ambọde nigba tọkunrin naa fẹẹ lọ fun saa keji nipo gomina ipinlẹ Eko, o ni ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ lasiko naa ki i ṣoju ọna rara, awọn o si le laju silẹ ki ilu Eko wọ’gbẹ.

Tinubu ni lati bii ọdun 2017 si 2018 lo ti n han kedere pe Ambọde ti yẹsẹ lori ila to ba nilẹ to yẹ ko maa tọ, eyi to le yẹ ko mu ilu Eko de ebute ayọ to jẹ afojusun awọn aṣaaju wa.

Tinubu sọrọ yii nibi ayẹyẹ ṣiṣi afara Pen-Cinema tuntun eyi to waye l’Agege, lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Tinubu ni bawọn agba oloṣelu ilu Eko ṣe ṣakiyesi awọn aṣiṣe ti gomina ana naa ṣe lo fa a ti wọn fi gbaruku ti Babajide Sanwo-Olu ati Igbakeji ẹ, Ọbafẹmi Hamzat, fun ipo gomina, bo tilẹ jẹ pe awọn o mọ, inu oun si dun pe awọn mejeeji ko ja araalu kulẹ.

O ni to ba jẹ awọn mi-in ni, wọn maa pa awọn iṣẹ ode tijọba ti wọn ba nilẹ ti ni, wọn aa tun bẹrẹ tuntun, ṣugbọn Sanwo-Olu ko ṣe bẹẹ.

Ọ rọ awọn araalu lati gbaruku ti iṣakoso to wa lode yii lati gbe ipinlẹ naa de ebute ogo.

Leave a Reply