Lati igba ti awọn eeyan pataki pataki ilẹ Yoruba kan ti lọ sọdọ Baba Reuben Faṣọranti ni Akurẹ, ti wọn ni awọn waa ba a gẹgẹ bii olori Afẹnifẹre, ki Aṣiwaju Bọla Tinubu le ṣalaye awọn eto to fẹẹ ṣe to ba di aarẹ, ni wahala gidi ti de ba wọn ninu Afẹnifẹre, ko si jọ pe wahala naa yoo lọ bọrọ, ti ki i baa ṣe pe ohun ni yoo lu ẹgbẹ naa fọ pata niyẹn. Lakọọkọ, awọn ti wọn pe ipade yii, ojulowo ọmọ ẹgbẹ Afenifẹre ni wọn, ṣugbọn nigba ti wọn pe ipade wọn, wọn ko sọ pe orukọ Afẹnifẹre lawọn fi pe e, orukọ Afẹnifẹre ko yọ nibi kankan. Igba ti wọn de ibi ti wọn n lọ ni wọn too sọ pe ipade Afẹnifẹre ni, bo tilẹ jẹ pe awọn naa mọ pe Faṣọranti ti kọwe fipo rẹ silẹ bii olori Afẹnifẹre. Bakan naa ni awọn ti wọn pepade yii mọ pe titi ti Oloye Ayọ Fasanmi fi ku ni bii ọdun meji sẹyin, awọn ti wọn lọ si Akurẹ yii ko gbagbọ gba Faṣoranti ni olori Afẹnifẹre, Fasanmi ni wọn ni awọn mọ, pe oun nikan ni olori ti awọn ni. Awọn ti wọn pepade yii mọ pe Baba Ayọ Adebanjọ ni ati araale ati araata mọ gẹgẹ bii olori Afẹnifẹre lati igba ti Faṣọranti ti loun o ṣe mọ. Eyi ni pe awọn ti wọn ṣeto ipade yii mọ pe jibiti lawọn fẹẹ fi orukọ Afẹnifẹre lu awọn araalu, ki awọn si fọ ẹgbẹ naa to ba fẹẹ fọ. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri jibiiti naa lu, nitori ọpọ onilaakaye lo ri i pe ori irọ ni wọn gbe ohun gbogbo ti wọn ṣe nibẹ si, ṣugbọn wọn yege ni ti pe wọn fọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, nitori yoo ṣoro ki ẹgbẹ naa too gberi pada bii tatijọ mọ. Ṣugbọn ki i ṣe Afẹnifẹre lawọn eeyan yii ba jẹ, wọn ba gbogbo ohun yoowu to ba jẹ ipilẹ eto oṣelu Yoruba jẹ, wọn sọ ẹgbẹ naa di yẹpẹrẹ ti ko le da si ọrọ oṣelu Naijiria lojukoju mọ, eyi to si buru ju ni pe wọn ko ni ẹgbẹ mi-in ti wọn yoo fi rọpo Afẹnifẹre ti wọn ba jẹ yii. Awọn eeyan yii mọ pe ko si ọna ti Faṣọranti yoo fi jẹ olori Afẹnifẹre mọ, ati pe Tinubu ti wọn tori rẹ ṣe eyi ti wọn ṣe yii ti ri ohun to fẹẹ ri nidii ọrọ naa, yoo pa wọn ti, ko si ni i da si wọn mọ, koda wọn ko ni i gba awọn ti wọn fi rugbẹẹ yii laaye lati ri i mọ fun igba pipẹ. Igba yii naa kọ ni akọkọ! Awọn naa ni wọn binu nigba kan naa ti wọn lọọ lati da ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal Group silẹ, nigba ti awọn ọdọ kan ni awọn ko fẹ bi awọn baba wọnyi ti n ṣe ẹgbẹ Afẹnifẹre. Ibẹrẹ ẹgbẹ naa dara, ṣugbọn wọn ko rin jinna ti awọn Aṣiwaju Bọla Tinubu yii kan naa fi ko wọ inu ẹgbẹ naa, ti wọn fa awọn kan mọra ninu wọn, to si jẹ nigbẹyin, wọn da ẹgbẹ naa ru, ọpọlọpọ awọn ti wọn si jọ wa ninu Afẹnifẹre Renewal ni wọn pada sinu ẹgbẹ Afẹnifẹre tawọn baba ti wọn n sa fun. Eyi ti wọn ṣe yii naa, lẹyin ti awọn ti wọn ṣe e ba mofo nibi ti wọn lọ, ti wọn padanu ohun gbogbo ti wọn tori ẹ ṣe eyi, wọn yoo pada sinu Afẹnifẹre yii kan naa pẹlu idọbalẹ, ṣugbọn nigba naa, Afẹnifẹre ko ni i wa lodidi mọ, awọn naa yoo si mọ pe awọn lawọn fọ ọ. Ko si ohun to buru lati ṣe atilẹyin fun Tinubu, koda ko si ohun to buru ti awọn Afẹnifẹre ba ni awọn fẹẹ tẹle e. Nigba ti Afẹnifẹre labẹ Adebanjọ si ti ni Peter Obi lawọn fẹẹ ba lọ yii, ko si ohun to buru ti awọn kan ba binu ninu ẹgbẹ naa, ti wọn ni awọn ko ba baba yii lọ. Ṣugbọn ohun to buru ni lati jade lọọ lo orukọ Afẹnifẹre laarin awọn ti wọn ti fibinu kuro ninu Afẹnifẹre. Ki lo wa ninu keeyan da ẹgbẹ tiẹ silẹ, ki lo wa ninu ki eeyan pe awọn agbaagba Yoruba lorukọ ẹgbẹ mi-in yatọ si ẹgbẹ Afẹnifẹre. Bẹẹ ohun ti awọn eeyan yii ṣe nibẹrẹ ree, orukọ ẹgbẹ mi-in ti i ṣe ẹgbẹ tiwọn ni wọn fi pepade yii, igba ti wọn depade ni apa wọn ko ka awọn ti wọn pe lọ sipade mọ, ti awọn yẹn ni ipade Afẹnifẹre lawọn wa, nigba ti awọn to si pepade ko mọ eyi ti wọn yoo ṣe mọ ni wọn da a si agidi, wọn bẹrẹ si i pa itan oriṣiiriṣii pe Faṣọranti ni olori ẹgbẹ Afẹnifẹre. Awọn naa mọ gbogbo jagajaga ti wọn ṣe yii, wọn mọ pe awọn ti fọ ẹgbẹ naa, iwọnba iyi yoowu to ba wa lara ẹgbẹ naa, awọn ti fi yi ẹrẹ pata. Bẹẹ ki i ṣe Afẹnifẹre yii ni wọn fi yi ẹrẹ, Yoruba ni. Wọn fi wa han aye bi alagbara-ma-mero, awọn ti iyapa ti ba laye jẹ. Ohun ti wọn ṣe fun Yoruba niyi! Awọn ti wọn ba nnkan yii jẹ naa ni ki wọn pada sẹyin kia, ki wọn ṣe atunṣe nibi to ba yẹ. Bi bẹẹ kọ, Yoruba ko ni i gbagbe orukọ wọn o, itan ti ko si daa ni wọn yoo maa sọ nipa wọn titi aye.