Ibi ti Tinubu ti n gba itọju lọwọ lo wa lorileede France – Adamu Waziri

Faith Adebọla

Ni iyatọ patapata si ọrọ tawọn amugbalẹgbẹẹ Aṣiwaju Bọla Tinubu sọ nipa irinajo rẹ sorileede France, ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ aṣeefọkantan ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Adamu Waziri, ti la a mọlẹ pe ibi tawọn dokita ti n tọju oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC ọhun, Bọla Tinubu, lo wa niluu Paris, lorileede France.

Waziri ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje, yii.

Ṣe lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa to kọja yii, ni amugbalẹgbẹẹ lori eto iroyin fun Bọla Tinubu, Ọgbẹni Tunde Rahman, kede ninu atẹjade kan pe ọga oun ti tẹkọ leti lọ siluu Paris, ni France, lati lọọ ṣe awọn ipade pataki kan, o ni ifikunlukun lori bi yoo ṣe jawe olubori sipo aarẹ ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 ati bi yoo ṣe yan igbakeji rẹ lo ba lọ.

Ọjọ keji ti Tinubu ti lọ ni Oludamọran pataki si Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ koto agbara ati gọta, Ọgbẹni Joe Igbokwe, gbe ọrọ kan sori ayelujara rẹ pe Tinubu lọọ ṣepade pẹlu Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ni. Ṣugbọn lọjọ keji ni Tunde Rahman ti gbe atẹjade kan sode pe irọ lọrọ yii, Wike ati Tinubu ko ṣepade kan, wọn o si rira rara.

Nigba ti wọn beere lọwọ Waziri pe ki lo ri sọ si bawọn alatilẹyin Tinubu ṣe n sọ pe yoo fẹyin Atiku Abubakar janlẹ yakata ni lasiko idibo sipo aarẹ, ọkunrin naa fesi pe:

“Ẹ jẹ ka jọ wo o, ohun ti o n sọ da bii pe ka ṣe ifiwera laarin eeso apu ati ọsan. Ni PDP, a ti ni oludije funpo aarẹ ati igbakeji rẹ, ni APC, wọn ni oludije funpo aarẹ to n ṣojojo, wọn o si ni igbakeji aarẹ.

“Ko ṣeni ti ko mọ pe oludije funpo aarẹ lẹgbẹ APC ko ni ilera gidi. Gbogbo wa la ri i lasiko idibo abẹle wọn, oludije wọn ko le di beba mu, niṣe ni aarẹ, alaga ẹgbẹ wọn ati iyawo ni lati ran an lọwọ ko too le ka ọrọ itẹwọgba rẹ jade, koda ko le da nikan di asia ẹgbẹ wọn mu, wọn ba a di i mu ni. Ṣebi gbogbo ẹ lẹ ṣafihan rẹ lori tẹlifiṣan yin yii.

“Ṣe o mọ pe minisita tẹlẹ lori ọrọ ọlọpaa ni mi, njẹ o mọ ibi ti Tinubu wa lọwọlọwọ ba a ṣe n sọrọ yii? O wa niluu Paris, nibi tawọn dokita rẹ ti n fun un ni itọju iṣegun.

“Gbogbo ohun ti mo mọ ni pe o n gba itọju iṣegun lọwọ ni, niluu Paris, o si wu mi pe ki ara ẹ tete ya, ko pada sibi, ka le sun un jẹ lagbo oṣelu ni tiwa.”

Ọkunrin naa tun sọ pe ẹgbẹ PDP ni Alaaji Rabiu Kwankwaso, oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ NNPP ati Peter Obi, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ Labour, yoo ṣiṣẹ fun.

Leave a Reply