Ibinu Alaaji bii ibinu Abija, Ọlọrun ma jẹ n ri i

Ka ṣa maa ṣe rere. Ṣe ẹ mọ pe gbogbo igba ni mo maa n wi bẹẹ. Ka ṣa maa ṣe rere o. Ani n ko mọ ohun ti mo fẹẹ fun awọn ọmọ ti mo ba ni ṣọọbu wa yẹn. Mo mọ pe ni gbogbo igba ti wahala wa yẹn, ti wọn ko ba si nibẹ loootọ, ti awọn ẹlẹgbẹ wọn mi-in ba kọja nibẹ ti wọn ri ṣọọbu ni ṣiṣi, wọn maa maa ko gbogbo ẹru nibẹ ni. Ṣe irẹsi ti wọn ba gbe ni ka ka iye ẹ ni abi apo ẹwa, abi awọn nnkan mi-in ni ṣọọbu keji, tabi owo ta a tiẹ ni nibẹ. Ṣugbọn emi ti gba kamu o, mo ti mọ pe gbogbo iyẹn ti lọ niyẹn, ba o ku iṣe o tan, bi ẹmi wa ba wa, ireti n bẹ.

Mo mo pe bi a ba wa laye ti a wa laaye, a oo ni ọja to ju eleyii lọ. O maa dun mi o, o maa dun mi pe mo sọ iru awọn nnkan bẹẹ nu, paapaa fun awọn ọmọọta ati awọn ole, ṣugbọn mo maa dupẹ lọwọ Olorun naa ni pe ẹmi eeyan kan o bọ si i. Mo ti mọkan, mo si ti gba pe ko sohun ti a le ri ninu ṣọọbu naa, paapaa nigba ti wọn ni ka ma jade, ta a tun n ri i bi wọn ṣe n fọ ṣọọbu, ti wọn n ko gbogbo ohun to wa nibẹ lọ, ati bi wọn ṣe n dana sun awọn mi-in. Iyẹn lo ṣe ya mi lẹnu nigba ti mo de ṣọọbu ti mo ba awọn ẹruuku, ti ṣọọbu wa digbi ti ko ṣẹni to debẹ.

Ko si iye ti wọn beere ti n ko ni i fun wọn. Ṣugbọn wọn o beere nnkan kan. Mo tun ni ki wọn jẹ ki n wọle ki n ko owo fun wọn, wọn ni irọ ni. Nigba ti mo ta ku ni wọn ni owo ounjẹ aarọ ọjọ naa nikan lawọn le gba lọwọ mi. Ani ọkan ninu wọn ni ṣe emi o mọ pe emi ti ran oun lọwọ nijọ kan to ṣoro foun ri ni. Ọlọrun si mọ pe emi o ranti rara, koda n ko da ọmọ naa mọ, igba to n sọ ọ yii naa ni mo too gbọ. Bi wọn ṣe gba iwọnba owo ti mo fun wọn ree, ni wọn ba lọ, la ba wọ sọọbu. Emi ati Safu. A ko gburoo Abbey ati Raṣida, awọn ọlẹ meji!

A o le pẹ ni ṣọọbu nijọ ta a kọkọ lọ naa, gbogbo adugbo lo da paroparo, nigba ti a si ti duro diẹ la ti tilẹkun, ẹni to ba fẹẹ raja ko pada wa nigba ti gbogbo nnkan ba rọlẹ. A si dupẹ bayii, gbogbo ẹ ti rọlẹ, onikaluku ti bẹrẹ iṣẹ ẹ pada, o kan jẹ oju apa ko jọ oju ara ni. Ki Ọlọrun ṣa maa fi iṣọ ẹ ṣọ wa, ohun to n da wahala silẹ ko to nnkan rara, bi wahala kekere bayii ba si bẹrẹ, bi wọn ko ba tete mura si i, yoo sare di nla ni. Ohun ti emi ri si gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii niyẹn. Akin gan-an royin o fi ti, o ni diẹ lo ku ki wọn ṣa oun ladaa.

Mo beere pe awọn wo ni wọn fẹẹ ṣa a ladaa, o ni awọn ọmọọta kan ti wọn waa ya ba awọn nibi ti awọn duro si ni sẹkiteeria ni. Niṣe ni mo pariwo, ‘Akin! O lọ si sẹkiteeria, ki lo wa lọ!’ Bi mo ba n sọrọ, ẹyin naa yoo ri i pe ki i ṣe pe mo kan n deede pariwo, awọn kan yoo si maa bu mi pe emi ti le jaya ku, pe Akin ki i ṣe ọmọde mọ. Ṣe iru ere egele to waa lọọ ṣe yii daa ni, abi kin ni ka ti pe e. Emi wa ni Oṣodi, oun ti kọja s’Ikẹja, bi wọn ba waa ṣe e lẹṣe lọhun-un nkọ! Kin ni mo fẹẹ maa wi. Ọlọrun ṣa ma jẹ kọmọ naa fi tiẹ ko ba mi.

Niwọnba igba ti a fi wa nile yẹn, a gbadun ara wa, emi ati Safu. Niṣe ni inu ọrẹ yin naa n dun ṣinkin, Aunti Sikira. Ọjọ meji ni wọn fun un pe ki Alaaji fi maa lọ sọdọ ẹ, ṣugbọn gbogbo igba ni yoo maa yọ wa, ti yoo maa waa mu Alaaji lọ. Mo ni ki Safu fi i silẹ, nitori mo mọ ohun to n ṣe e. Ohun to n ṣe e naa ni pe o fẹ ki Alaaji tun fẹran oun pada bii ti tẹlẹ, ki wọn tun jọ maa ṣe bi wọn ti n ṣe. Ṣugbọn mo mọ pe iyẹn o ni i ṣee ṣe. Mo mọ ẹni ti mo ni, bi ọrọ ba ti ri bo ṣe ri yii, iru ọrọ bẹẹ ki i tete tan ninu Alaaji. Ọkọ mi buru bo ba jẹ tiyẹn ni.

Bobinrin ba ti ṣe iru ohun ti Aunti yii ṣe yii, bi ko ba ṣọra, bọya ni Alaaji yoo tun gori ẹ mọ, yoo kan maa yi i sori ebe, ti yoo maa yi i si poro ni, nigba naa ni yoo ni ara oun ko ya, ti yoo maa wa oriṣiiriṣii alaye ti ko kun ajọ ṣe. Nigba ti Safu si fẹẹ maa binu pe ṣe lojoojumọ ni wọn tun n ri ara wọn bayii ni, mo ni ko jokoo ẹ jẹẹ,ko maa woran, mo waa sọ ohun to n ṣẹlẹ fun un. O ni ṣe Alaaji lo sọ bẹẹ femi ni, mo ni Alaaji ko ni i sọ fun mi, ṣugbọn ṣe ko mọ iye ọdun ti emi pẹlu ẹ ti jọ wa ni, bawo ni n ko ṣe ni i mọ bi nnkan kan ba n ṣe e, tabi iru iwa to le hu.

Safu si sọ fun mi nijọ kẹta pe ti mo ba n woṣẹ, mo maa jẹun. Mo ni ki lo de to fi wi bẹẹ. O ni Aunti Sikira lo waa ba oun ninu ile nigba to ri i pe Alaaji lọ sọdọ iyaale wa agba, lo ba sọ foun pe ki oun ba oun bẹ ọkọ oun, pe ko ma binu, ko gbagbe ọrọ to ti lọ, nitori ko sun mọ oun lati ọjọ ti a ti lọọ mu oun bẹbẹ yẹn o, to ba ti wa to ti jẹun, o maa gba yara ẹ lọ pada ni. Ọjọ to ba si sun toun naa, o maa sun kaaka, ti yoo maa han-an-run ni o, bi oun si fọwọ pa a lara titi, ara ẹ ko ni i dide o. Niṣe ni mo miri titi, nigba ti n ko sinmi ni Safu ni ki lo de.

Mo ni bawo ni agbalagba ṣe n ya alailojuti bayii. Ṣe oun lo tun yẹ ki Aunti Sikira maa fi iru ọrọ bẹẹ lọ. Ṣebi oun naa yoo ni suuru ki inu ọkọ ẹ fi rọ, ti inu ẹ ba si ti rọ, ṣebi yoo mọ bi yoo ṣe tubọ bẹ ẹ ni. Ọkunrin meloo lo le gba iru iyẹn, ki wọn ni wọn ka ẹ mọ ile ale, nibi ti ẹ ti n ba ara yin sun, ki iyawo onitọhun ka yin mọ, ko o sare jade debii pe o gbagbe pata, ko o waa ni ki ọkọ ẹ ti tun maa sare gori ẹ. Mo tiẹ jẹrii ọkọ temi o, gbogbo nnkan lọmọ ọba o ni, bii ti dansaki kọ. Bo ṣe wa yẹn, ko ma jẹ ohun ti yoo ba kuro nile Alaaji niyẹn. Alaaji ti inu ẹ le buruku.

Bo ba tiẹ wa jẹ iru ọrọ bayii ni, yoo ko agidi bori ni, bẹẹ ni yoo maa rẹrin-in, ti ko ni i sọ ohun to fẹẹ ṣe gan-an. Ṣugbọn ẹnu temi kọ leeyan yoo ti gbọ iru ẹ, eyi to fẹ ki n ṣe ni mo ti ṣe yẹn, mo ti ba a bẹ ọkọ ẹ, mo si ti le awọn famili kuro nidii ọrọ ẹ, oun lo ku ko yanju ara ẹ. Ohun ti oun ko ti i mọ ni pe iru ọrọ bẹẹ yẹn le lọkan Alaaji ju keeyan pa a lọmọ lọ, ibinu Alaaji to jẹ bii ibinu Abija ni, Ọlọrun ma jẹ n ri i.

Leave a Reply