Ibo 1979 ku si dẹdẹ, n lawọn adigunjale ba ko girigiri ba awọn oloṣelu atijọba Ọbasanjọ (3)

Igba kan ti wa nilẹ yii to jẹ iṣẹ ọlọpaa a maa wuuyan i ṣe, nitori awọn ọlọpaa Naijiria ni apọnle lara pupọ. Ti kinni kan ba ṣẹlẹ to jẹ nnkan aidaa, ti wọn ba ti pe wọn si i, bii ọmọde-meji-n-ṣere ni wọn yoo ti wadii ọrọ naa, ti wọn yoo si tu aṣiri ohun gbogbo to ṣẹlẹ sita. Bi ọrọ awọn adigunjale to ja N80,000, owo ileeṣẹ Boulos, gba, ti wọn pa ọlọpaa meji, ti wọn si ri i pe ọkan to ku fara pa gidigidi, ṣe ri gan-an niyẹn. Nitori pe ọrọ naa ko jinnijinni ba gbogbo ilu, lẹsẹkẹsẹ lawọn ọlọpaa yii ti bẹ sita, nigba ti yoo si fi to ọsẹ kan bayii, aṣiri ọrọ naa ti bẹrẹ si i tu si wọn lọwọ. Bẹẹ ki i ṣe pe awọn adigunjale naa duro soju kan, wọn ko duro rara. Bi wọn ti ja owo ọhun gba ni wọn sare pade ara wọn nibi kan ti wọn ti ṣeto ni Ọgba. Nibẹ ni wọn fi ipade si, nibẹ ni gbogbo wọn si ti pin owo ti wọn ja gba naa, ti kaluku ba tirẹ lọ.

Bi wọn ṣe pin owo naa ni pe Nelson Diefah ti i ṣe ọga iṣẹ yii gba ẹgbẹrun mejila Naira, Sam Dag, iyẹn Youperer Dakoru, gba ẹgbẹrun mejila, eyi ti wọn n pe ni Igun (Vulture) ninu wọn naa gba ẹgbẹrun mejila, Boniface, ti Albert naa si gba ẹgbẹrun mejila mejila, Umukoro gba ẹgbẹrun mẹwaa, William Douglas naa si gba ẹgbẹrun mẹwaa to wa fun oun ati awọn ti wọn ba wọn wa iṣẹ naa. Bi wọn ti pin owo naa tan ni kaluku da ibọn pada fẹni to ni wọn, wọn si fọnka bii ẹni ti ko tilẹ mọra ri, tabi bii ẹni to ti paayan meji laaarọ ọjọ naa, wọn gba ile wọn lọ. Bi awọn ọlọpaa ti de ibi iṣẹlẹ naa ti wọn si ko awọn oku to ku, ti wọn ṣa awọn ọta ti wọn lo nibẹ, wọn ti ri awọn ohun mẹta kan. Akọkọ ni pe ọna ti wọn gba ṣe iṣẹ naa fi han pe awọn ti wọn mọ nipa iṣẹ ologun ni wọn ṣe e, ẹẹkeji si ni pe ọta ibọn awọn ṣọja ni wọn lo.

Eyi ni pe ọrọ naa ti fẹsẹ mulẹ lọna tibẹ yẹn. Awọn ọlọpaa ti mọ pe bi ko ba jẹ awọn ti wọn ṣi wa ninu iṣẹ ologun ni wọn ṣiṣẹ yii, aa jẹ awọn ti wọn ti kuro nibẹ, boya wọn le wọn tabi wọn lọ funra wọn. Ọna kẹta si ni pe ọrọ naa ko le ṣẹlẹ bi ko ba ni ọwọ araale ninu. Wọn mọ pe kinni naa ti bọ soju ẹ ju. Bawo ni wọn ṣe mọ pe wọn n gbe owo lọ? Ki lo de ti wọn ko da mọto mi-in duro to jẹ eyi to n gbowo lọ gan-an ni wọn da duro? Bawo ni wọn ṣe mọ iye ọlọpaa to wa ninu ẹ ati ibi towo wa? Awọn ọlọpaa mọ pe ko sẹni to le fun awọn adigunjale ni itọsọna yii ju araale to ti mọ bi wọn ti n gbowo kuro ni ileeṣẹ Boulos ati igba ti wọn n gbe e lọ.  Nidii eyi, awọn oṣiṣẹ ileeṣe Boulos ti wọn wa ninu mọtọ funra wọn ni wọn kọkọ mu, ti wọn si rọ wọn da sitimọle lẹsẹkẹsẹ, paapaa akauntanti ileeṣẹ naa to n gbowo ọhun lọ.

Nibi ti wọn ti n tẹ akauntanti wọn yii ati dẹrẹba mi-in ti wọn tun mu ninu ni wọn ti tule kan Johnson Ibekwe. Kuku (cook) ni Ibekwe, ọdọ ọga kan ninu awọn ọga ileeṣẹ naa lo si ti n ṣiṣẹ, iṣẹ ile ni iṣẹ ẹ, ki i ṣe gbogbo igba ni i wa sinu ọgba. Ṣugbọn lọjọ iṣẹlẹ yii, wọn ri kuku naa nibi iṣẹ, koda o wa ninu awọn to ran wọn lọwọ lati gbe owo sọkọ. Nigba tawọn ọlọpaa yoo fi gbọ eyi ṣaa o, ti wọn yoo si sare pe ki wọn wa Ibekwe lọ, ẹran ti lọ! Ko dagbere to fi sa lọ si ilu wọn, ni ilẹ ibo lọhun-un. Lẹsẹkẹsẹ tawọn ọlọpaa gbọ naa ni wọn ti gbe mọto jana, nigba ti yoo si di ọjo keji, wọn kan an lara ni Uzuakoli, nipinlẹ Imo, nibẹ ni wọn ti gbe e janto. Wọn beere pe ki lo waa ṣe nile, o ni oun sare waa wo iyawo oun to loyun ni, nitori oun gbọ pe ara rẹ ko ya. Ki lo waa de ti ko dagdere, o ni ko si ọga oun nile, iyawo rẹ loun dagbere fun.

Nibi yii lọrọ ti bẹrẹ si i loju o, nitori nigba ti wọn wọ Ibekwe de Eko, kia lo bẹrẹ ẹjọ ẹnu ẹ bii ẹni ti wọn ti irin gbigbona bọ labẹ, oun lo si fa wọn de ile Jimmy, nigba ti wọn ko si ri Jimmy, o mu wọn, o di ile Nelson Diefoh, ẹni to wa nidii eto gbogbo. Aarin ọsẹ kan ni wọn fi ṣe gbogbo eleyii, nigba ti wọn si ti ri Diefah, to jẹ ibi kan ti ko loluwa ninu ile Festac lo n gbe, ti wọn si mọ pe ṣọja to sa lẹnu iṣẹ ni, wọn ti mọ pe ẹni ti awọn n wa niyẹn, ki awọn mu un daadaa lo ku. Nibi yii lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ wọn. Nigba ti iya dun Diefah yii, o jẹwọ fun wọn, o loun gan-an lọga ẹgbẹ adigunjale naa, ko si sohun to ṣẹlẹ lọjọ yii toun ko mọ, bi wọn ba ni suuru, oun yoo ṣalaye gbogbo rẹ fun wọn. N ni Diefah ba tẹnu bọrọ loootọ, oun lo si jẹ ki wọn mọ bi ọrọ naa ṣe lọ. O ni loootọ oun loun dari idigunale naa, ṣugbọn oun kilọ gidi fawọn eeyan oun pe wọn ko gbọdo paayan, Sam Dag ni ko gbọrọ soun lẹnu to fi ba gbogbo nnkan jẹ.

Nibi yii lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ si i wa Sam Dag, ki wọn too ṣẹṣẹ waa mọ pe ẹni ti awọn ti n wa tẹlẹ ni, orukọ rẹ gan-an si ni Youpere Dakuro. Wọn n wa a nitori o sa jade kuro ni sẹẹli Adeniji Adele ni, oun ati awọn ọdaran kan ni wọn jọ ja ilẹkun-irin ibẹ, ti wọn si sa jade lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun naa, iyẹn ni pe bii ọsẹ kẹta to sa kuro ni sẹẹli  lo lọọ ba wọn jale, to si pa ọlọpaa meji. Ohun to jẹ ko wa ni sẹẹli ni pe wọn ti digunjale kan ni Badagiri tẹlẹ, nibẹ lo ti pa ọlọpaa kan, iyẹn ni wọn n tori ẹ ba a ṣẹjọ to fi wa ni sẹẹli, ko too di pe wọn jalẹkun jade. Nigba ti wọn beere bo ṣe sa jade lẹwọn, o ni ki i ṣe oun loun ṣeto ẹ, ọkan ninu awọn ọdaran to wa nibẹ to n jẹ Lobito ni, nigba ti oun si ri awọn ẹlẹwọn to ku ti wọn n sa jade, ko si bi oun ṣe le maa duro woran, n loun naa ṣe sa jade. O ni Ṣaṣa, nitosi Agege, loun sa lọ.

Bẹẹ si ni, ni Ṣaṣa lawọn ọlọpaa ti lọọ tu u jade, Diefa lo mu wọn dele ẹ nigba tawọn ọlọpaa ṣe ṣege fun un. Ọrẹ lawọn mejeeji. Ọrẹ gidi ni wọn paapaa. Nigba  ti Dakuro jade lẹwọn to farapa rẹpẹtẹ, Dieah lo mu un lọ si ọdọ wolii kan, Pasitọ Samson Amosun, ẹni to ni ṣọọṣi rẹ si Ojule kẹrindinlọgbọn, Opopo Ọlanibi, ni Papa Ajao,  Muṣin. Diefah sọ fun Amosun pe ijamba mọto ni Dakuro ni, ko ba oun gbadura fun un ko le gbadun. Niyẹn ba bẹrẹ adura loootọ, nigba ti wọn si gbadura tan, wọn lọ. Ko pẹ ni Diefoh tun pada lọ si ọdọ pasitọ naa, to ni oun fẹ ko gbadura foun ki oun ba ojurere awọn ọlọpaa pade, nitori onimọto loun, tirela meji loun si ni lọna, oun fẹ ki wọn gbadura ki awọn mọto naa lọ daadaa, ki won bọ daadaa. Ni Pasitọ Amosun ba tun bẹrẹ adura, adura ti pasitọ yii gba, ati ogoji Naira (N40) ti wọn fun un lo sọ ọ di ero atimọle, diẹ lo si ku ki wọn mu un mọ awọn adigunjale naa.

Dakuro ko parọ ọrọ naa mọ nigba ti kinni ọhun ti de oju ọgbagade. O jẹwọ fawọn ọlọpaa, o ni loootọ loun ti pa ọlọpaa kan ni Badagiri nigba ti awọn lọọ jale nibẹ ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja, nibi ti iṣẹ ti awọn si ṣe ni Ikẹja, oun ko fẹ ki awọn ọlọpaa ti wọn n ṣọ owo naa, tawọn naa si gbebọn dani di awọn lọwọ loun ṣe mu wọn balẹ, ki iṣẹ awọn le ya ni. O ni oun ti ri owo daadaa nidii iṣẹ naa nitori laarin ole mẹta pere ti awọn ja laipẹ sigba naa, ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira loun ti ri. Ni tootọ, owo nla leleyii nigba naa. Diefah naa lo ṣe e ti wọn fi ri Lawrence Edemirukewu mu, oun ni ọlọpaa mopo to na awọn adigunjale naa wa ọta ibọn. Williams Douglas lo mọ ọn, oun lo si ṣeto ọta ibọn naa. Oun naa kuku tiẹ jẹwọ, o ni loootọ loun mọ Douglas, ọmọ Ajegunlẹ jọ lawọn mejeeji, oun ko kan mọ ohun to n sọ nipa ti ọta ibọn yii ni.

Ẹni to gbe panla ti jẹwọ, ọrọ ko si pariwo mọ. Awọn ọlọpaa ko gbogbo awọn adigunjale mẹfẹẹfa, o di iwaju igbimọ ologun to n gbọ ẹjọ awọn adigunjale, wọn ni ki wọn da ẹjọ to ba yẹ fun wọn. Bẹẹ ni ẹjọ naa bẹrẹ lọjọ kẹta, oṣu karun-un, lai ti i pe oṣu kan ti iṣẹlẹ naa ṣẹ, niwaju Adajọ K. A. Hotonu ni.

Leave a Reply