Oluṣẹyẹ Iyiade
Lasiko ti Tinubu ṣabẹwo sawọn aṣaaju ilẹ Yoruba lọjọ Aiku, Sannde, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa yii, nibi to ti sọ gbogbo erongba rẹ ati awọn nnkan ribiribi to maa gbe ṣe to ba de ori ipo tan lawọn agbaagba ẹgbe Afenifẹre to wa nibi ijokoo naa ti fi i lọkan balẹ pe gbogbo ara lawọn yoo fi ti i lẹyin lati de ilẹ ileri naa. Lẹyin eyi ni wọn sọ pe ko kunlẹ, wọn si rojọ adura le e lori. Alagba Faṣoranti tilẹ gbe ọwọ le e lori ni, wọn si bẹrẹ si i wure fun un pe Olodumare yoo ran an lọwọ lati de ori ipo to n wo niwaju rẹ ọhun.
Ṣaaju akoko yii ni Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe adari eto iroyin fun ikọ ipolongo ibo fun ẹgbẹ APC, ti kede ọrọ naa ninu atẹjade to fi lede. Nibẹ lo ti sọ pe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, yoo gbe aba eto iṣejọba atawọn nnkan to fẹẹ ṣe siwaju Alagba Reuben Faṣoranti atawọn aṣaaju Afẹnifẹre mi-in niluu Akurẹ fun ibuwọlu wọn.
Lara awọn to wa nibi ipade na ni Oloye Olu Falae, Ọtunba Gbenga Daniel, Ọjọgbọn Isaac Adewọle, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyo, Bayọ Lawal ati bẹẹ bẹẹ lọ.