Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọwọ ajọ to n gbogun ti lilu owo ilu ni ponpo ati iwa ajẹbanu (EFCC), ẹka ti ipinlẹ Eko, ti tẹ ayederu aafaa kan, Abiọdun Ibrahim, ati ayederu babalawo kan, Wale Adifala.
Bakan naa ni ajọ naa tun kede pe awọn n wa Ọgbẹni Ifawọle Ajibọla, to pe ara rẹ ni babalawo.
Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn sọ pe wọn gbimọ-pọ lati lu ọmọ ileegbimọ aṣofin kan l’Abuja to n ṣoju ẹkun idibo ati agbegbe Ọyẹ/Ikọle, nileegbimọ aṣofin kekere, Ọnarebu Peter Owolabi, ni jibiti.
Aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Onigbaalẹ (APC), to n ṣoju agbegbe naa lọwọlọwọ lo padanu ipo naa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ yii to waye ninu oṣun Karun-un, ọdun yii, ṣọwọ Ọgbẹni Akin Rotimi.
Ọnarebu Owolabi ni wọn sọ pe awọn onijibiti yii gba milliọnu lọna mẹrinlelogun lọwọ rẹ lati le ba a ṣe eto adura ati ẹbọ, ki ẹgbẹ naa le pada mu un gẹgẹ bii ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ wọn lati agbegbe Ọyẹ/Ikọle ninu eto idibo ọdun 2023 ni Abuja.
Ọwọ EFCC tẹ awọn ọdaran ọhun lọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2022, ni Ado-Ekiti, ni kete ti aṣofin yii kọ lẹta si ajọ EFCC pe wọn gba owo lọwọ oun pẹlu ileri pe ẹgbẹ APC yoo pada fa oun silẹ lẹẹkeji, eleyii ti ko ri bẹẹ.
Nigba ti EFCC n fọrọ wa wọn lẹnu wo, Adifala jẹwọ pe loootọ ni awọn gbowo lọwọ aṣofin naa, ṣugbọn miliọnu mẹta din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N2.9m) pere lawọn gba lọwọ Owolabi.
O ṣalaye pe awọn gba owo naa lati fi ra maaluu ati agbo dudu, funfun ati alawọ pupa. O fi kun un pe awọn tun ra lọfinda olooorun didun, ooka ati awọn oun eelo miiran tawọn yoo fi rubọ, ati eyi tawọn yoo lo lati fi ṣiṣẹ naa.
Adifala ṣalaye pe ni kete ti oun gba iṣẹ naa ni oun kan si Ifawọle Ajibọla tawọn yoo jọ ṣe irubọ naa, ti wọn si bẹrẹ titi di asiko ti awọn EFCC fi waa mu awọn.
Adifala sọ pe babalawo ati aafaa to daju ni awọn, ṣugbọn gbogbo ipa ni awọn sa, ti awọn si ru gbogbo ẹbọ lati ri i pe aṣofin naa pada si ile-igbimọ aṣofin lẹẹkeji, ṣugbọn ọwọ Ọlọrun lo wa bi ẹgbẹ naa ko ṣe pada mu aṣofin ọhun lẹẹkeji, ati bi ẹgbẹ Onigbaalẹ ṣe gbe ipo naa lọ si ilu miiran.