Jọkẹ Amọri
Olori awọn to n ja fun ominira orileede Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akitoye, ti kọwe kan jade, nibi to ti ṣapejuwe gbogbo erongba oludije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bii ẹni to n ja fun ara rẹ nikan, ti ko nifẹẹ awọn ẹya rẹ lọkan rara. Ninu atẹjade naa to tẹ ALAROYE lọwọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, lo ti sọ pe pẹlu ariwo, ‘emi lo kan’ ti Tinubu n pa kiri, o fi han pe erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria wa fun imọtara rẹ nikan, ki i ṣe fun awọn ẹya Yoruba rara.
Baba yii wẹ ọwọ rẹ mọ, o si sọ pe ohun ko mọ ohunkohun nipa awọn ti wọn n sọ pe oun n ṣatilẹyin fun Tinubu lati dupo aarẹ, pẹlu bi wọn ṣe lọọ ge diẹ ninu ifọrọwerọ ti oun ṣe pẹlu iweeroyin ALAROYE ni nnkan bii ọdun meji sẹyin, ti wọn si n lo abala naa lati sọ pe oun n ṣatileyin fun Tinubu lati di aarẹ Naijiria. O ni asiko ti ko tọ, ti ko si tọna, rara ni Tinubu jade si lati di aarẹ.
Baba to gba oye imọ ijinlẹ lori ẹkọ nipa Itan (History), yii sọ pe oun ko ṣatilẹyin fun Tinubu, beẹ loun ko ni i dibo fun un lọdun to n bọ. Akintoye naka abuku si ọpọ awọn oloṣelu ọmọ Yoruba ti wọn n du ipo oṣelu kan tabi omi-in. O ni wọn n ṣe eleyii lodi si awọn ti wọn n ja ijangbara fun idasilẹ Orileede Yoruba.
Oludari ẹgbẹ Ilana Oodua yii sọ pe oun ko ni ikunsinu kankan fun eyikeyii ọmọ Yoruba to ba fẹẹ du ipo oṣelu kan tabi omi-in, ṣugbọn aanu wọn ṣe oun nitori itiju ni igbesẹ ti wọn n gbe yii yoo jẹ fun awọn ọmọọmọ wọn lọjọ iwaju.
Eyi ni bi iwe ti baba agbalagba yii gbe jade ṣe lọ.
‘‘Arakunrin wa, Tinubu, o n ja fun ara rẹ, nigba ti awọn mọlẹbi rẹ n ṣegbe. Ina nla lo wa lori orule wa bayii gẹgẹ bii orileede. O jẹ ohun ti ko ṣee gbagbọ pe ẹni kan gẹgẹ bii ọmọ Yoruba yoo ṣe ohun ti o n ṣe yii fun iran Yoruba lapapọ. Fidio ifọrọwerọ ti mo ṣe pẹlu iweeroyin ALAROYE ninu ọgba Ọbafẹmi Awolọwọ Yunifasiti ni bii ọdun meji sẹyin lo n gbe kiri. Wọn beere lọwọ mi pe ti ko ba si ijangbara kankan lori ọrọ ominira fun ilẹ Yoruba, ta ni mo le fa kalẹ lati ṣe aarẹ ilẹNaijiria. Mo si sọ fun wọn pe ti ko ba si pe a n jijagbara, mo le fa Tinubu kalẹ lai ro o lẹẹmeji, iyẹn to ba jẹ pe ohun gbogbo ri bo ṣe yẹ ko ri nigba naa, ṣugbọn gbogbo nnkan ko ri bo ṣe yẹ ko ri lasiko yii. Mi o fọwọ si ọmọ Yoruba kankan, boya Tinubu tabi ẹnikẹni fun ipo oṣelu kankan ni asiko yii rara ni Naijiria. Mo duro digbi, lai yẹsẹ, lai boju wẹyin fun ijangbara awa ọmọ Yoruba, iyẹn lati ni orileede tiwa ti i ṣe Yoruba Nation.
‘‘Otitọ to wa ninu ọrọ yii ree o, Tinubu, mi o fẹ ki o tan ara rẹ jẹ, mi o si fẹ ki o tan awọn eeyan wa jẹ. O ro pe o le maa gbe iru fidio yii kiri ko o maa fi tan awọn eeyan wa, awọn eeyan wa ti gbọn ju bayii lọ. Gbogbo agbaye lo n wo ọ. Itan yoo si ṣe idajọ rẹ pe lasiko ti a nilo lati dide duro lati gbeja awọn eeyan wa ni o n ba ọrọ ti ara rẹ nikan kiri. Ọrọ ti ara rẹ nikan to wa fun ifẹkufẹẹ ara rẹ funra rẹ lo n gbe wa siwaju wa, o n beere pe ka dibo fun ọ. Awa ko ni i dibo fun ọ o. Boya fun ipo aarẹ ni, ileegbimọ aṣofin agba ni tabi ileegbimọ aṣoju-ṣofin, awa ko ni i dibo fun ọ, nitori awa yoo ti mu orileede wa kuro lara Naijiria lasiko yẹn. Nidii eyii, a n gba ọ niyanju pe ki o pada sọdọ awọn eeyan rẹ. Emi gẹgẹ bii ẹni kan n gba ọ niyanju pe ki o pada sọdọ awọn eeyan rẹ, ki o si fọ ọkan rẹ mọ, nitori o n ṣe awọn ohun ti yoo ṣoro lati dariji ọ.
‘‘Tinubu, o n ba ọjọ ọla ilẹ Yoruba jẹ. O n ṣe agbekalẹ ogun fun ara rẹ, eyi ti yoo jẹ itiju fun awọn ọmọọmọ rẹ lati mọ lọjọ iwaju. A n pe ọ pe ki o pada wale. Anfaani wa fun ọ nisinsinyii lati gba ara rẹ ati ọjọ iwaju rẹ kalẹ. A ti ni ipinnu lati gba orileede wa. Digbi digbi ni mo si wa lẹyin awọn ọdọ to n sare kaakiri lati gba orileede wọn. Loootọ o le sọ pe wọn n ba ara wọn ja, eyi ko jẹ tuntun, bawọn ọdọ ṣe maa n ṣe kaakiri orileede agbaye niyi. Eleyii ko si sọ pe wọn ko fẹ orileede wọn, wọn fẹ orileede wọn. Ọlọrun Oluwa to da gbogbo orileede si ti fun wọn ni orileede naa, laipẹ lai jinna, Ọlọrun yoo si fi orileede wọn le wọn lọwọ. Yoo waa jẹ ojuṣe wọn lẹyin eyi lati jokoo, ki wọn si bẹrẹ eto ijọba ti Yoruba maa n ṣe fun awọn eeyan rẹ lati ipilẹṣẹ wa, ijọba to ni erongba lati mu igbe aye rere ba awọn eeyan orileede rẹ.’’
Tẹ o ba gbagbe, lọdun bii meji sẹyin ni Ọjọgbọn Akintoye ṣe ifọrọwerọ pẹlu iweeroyin ALAROYE, nibi to ti ṣalaye pe to ba jẹ pe gbogbo nnkan ri bo ṣe yẹ ko ri, oun iba ni Tinubu ni ki wọn fa kalẹ funpo aarẹ ilẹ wa, ṣugbọn nitori gbogbo nnkan ko ri bẹẹ, ati pe asiko ti ọkunrin naa le ṣejọba Naijiria ti kọja, bi a ṣe maa ni Orileede Yoruba wa lo ṣe pataki. Diẹ lara fidio ifọrọwerọ yii lawọn kan fa yọ ti wọn fi n gbe e kiri pe baba naa ti n ṣatilẹyin fun Bọla Tinubu latu dupo aarẹ Naijiria. Ṣugbọn Baba Akintoye ti fọ ara rẹ mọ lori fidio to pe ni jibiti ti wọn n gbe kiri ọhun, o ni oun ko ṣatilẹyin fun ẹnikẹni. Orileede Yoruba ni oun nigbagbọ ninu rẹ, digbi loun si wa lẹyin awọn ti wọn n ja fun un.