Ibo aarẹ: Ile-ẹjọ gba awọn iwe esi idibo ti Peter Obi ko lọ si kootu gẹgẹ bii ẹri

Monisọla Saka

Ọgbẹni Peter Obi, ti i ṣe oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, nibi eto idibo aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ti ṣalaye niwaju ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ nibi eto idibo ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, pe ipinlẹ mejidinlogun pere ni awọn ti jawe olubori, tawọn ko si fara mọ esi idibo ti ajọ INEC kede nibẹ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo yẹ ki igbẹjọ ẹsun tawọn ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Peter Obi pe waye, ṣugbọn ti wọn bẹ adajọ lati ba wọn sun un si Ọjọbọ, Tọsidee, nitori meji ninu awọn ikọ agbẹjọro wọn tara wọn ko ya.

Niwaju awọn igbimọ adajọ ẹlẹni marun-un, eyi ti Adajọ Haruna Simon Tsammani ṣaaju wọn, lawọn olupẹjọ ti sọ pe awọn ko ni i kawọ bọ’tan, ki ọrọ naa lọ bẹẹ lawọn ipinlẹ to da awọn loju pe awọn lawọn wọle nibẹ.

Ipinlẹ mẹfa, ninu mejidinlogun tawọn Obi sọ pe awọn n tori ẹ pẹjọ ni wọn ti ko ẹri wa. Wọn ni lati ọdọ ajọ INEC, lawọn ti gba awọn iwe naa. Awọn iwe yii ni wọn fẹẹ lo ta ko ajọ INEC, Aarẹ Bọla Tinubu, ati Igbakeji rẹ, Sẹnetọ Kashim Shettima, ti wọn jẹ olujẹjọ kin-in-ni, ikeji ati ikẹta, lati fidi ododo mulẹ lori magomago atawọn iwa ibajẹ mi-in ti wọn sọ pe wọn hu lasiko ibo.

Bo tilẹ jẹ pe Onidaajọ Tsammani gba iwe ti Oloye Emeka Okpoko to ṣoju ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Peter Obi ko kalẹ gẹgẹ bii ẹri, agbẹjọro ajọ INEC, Kẹmi Pinhero, ni ojulowo lawọn iwe ọhun, amọ o kọ jalẹ lati gba iwe naa wọle.

Bakan naa ni Adebayọ Adelọdun, agba lọọya to duro fun Tinubu ati Shettima ti wọn jẹ olujẹjọ keji ati ikẹta, kin Pinhero lẹyin, nigba toun naa lodi si iwe idibo wọọdu kọọkan ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party fi lelẹ gẹgẹ bii ẹri niwaju ile-ẹjọ.

Bẹẹ ni agbẹjọro fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Oloye Afọlabi Fashanu, naa fidi ẹ mulẹ pe oun naa yoo ta ko iwe tawọn agbẹjọro Peter Obi ati ẹgbẹ oṣelu wọn gbe siwaju ile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹri, ninu eyi ti esi idibo aarẹ ni wọọdu mẹẹẹdogun nipinlẹ Rivers, mẹtalelogun nipinlẹ Benue, mejidinlogun nipinlẹ Cross River, mẹtalelogun nipinlẹ Niger, ogun ni Ọṣun ati mẹrindinlogun l’Ekiti wa.

Nikẹyin, lẹyin ti meji ninu awọn olupẹjọ ti da a labaa, adajọ kede ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, bi ọjọ ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.

 

Leave a Reply