Ibo abẹle APC: Awọn gomina lati ilẹ Yoruba tun wọle ipade

Jọkẹ Amọri Pẹlu bi awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe din oludije wọn lati marun-un to kọkọ wa tẹlẹ si mẹta laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, to jẹ ọjọ idibo naa, awọn gomina ilẹ Yoruba to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC ti tun wọle ipade mi-in.
Ohun ti ipade yii da le lori gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni bi wọn yoo ṣe tun din awọn mẹta to ku naa ku si ẹyọ kan pere, ti awọn meji to ku yoo si juwọ silẹ fun un.
Ba a ṣe n kọ iroyin yii, ipade naa ṣi n lọ lọwọ, ṣugbọn ko sẹni to ti i le sọ boya awọn eeyan naa yoo fagba fun ẹni kan, abi pe wọn yoo jọ lọọ wa a ko ni gbangba ibi ti eto idibo yoo ti waye ni.
Awọn mẹta to ku naa ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọ Yẹmi Ọṣinbajo, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Rotimi Amaechi.

Leave a Reply