Ibo abẹle APC l’Ondo: Eyi ni orukọ awọn ti yoo kopa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Mọkanla ninu awọn oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ondo ni wọn ti peregede ninu ayẹwo tí wọn n ṣe lọwọ lati mọ awọn to kun oju oṣuwọn lati kopa ninu eto ibo abẹle ti yoo waye logunjọ, osu ta a wa yii.

Alaga igbimọ oluṣayẹwo ọhun, Alaaji Tijani Tumsa, lo ṣe alaye yii lọsan-an oni ti i ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee.

Alaga naa ko ti i fi orukọ oludije ti wọn fagi le sita ninu awọn mejila to gba fọọmu lati kopa ninu eto ibo abẹle naa.

Eyi lawọn to gba fọọmu idije ninu ẹgbẹ:

Gomina Rotimi Akeredolu, Abilekọ Jumọkẹ Anifowoṣe, Oluṣọla Iji, Jimi Ọdimayọ, Ọlayide Adelami, Kekemeke Isaac, Oluṣọla Oke, Ifẹoluwa Oyedele, Awodeyi Akinsẹhinwa, Olubukọla Adetula, Ṣẹgun Abraham ati Nathaniel Adojutẹlẹgan.

 

Leave a Reply