Gbenga Amos
Pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ṣe kede pe ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn yoo ṣeto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo dije funpo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ naa, Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti tẹsiwaju ninu ifikunlukun rẹ lati jawe olubori nibi eto idibo abẹle ọhun.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta yii, l’Ọṣinbajo wọle ipade pẹlu awọn alenulọrọ ati agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ. Gbọngan apero nla ti Ibadan Civic Centre, eyi to wa lọna Iwo, n’Ibadan, nipade naa ti waye.
Gbogbo awọn aṣoju ati ijoye ẹgbẹ lati ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Ọyọ ni yoo fori kori pẹlu oludije pataki yii.
Ba a ṣe gbọ, ifikunlukun Ọṣinbajo da lori bi ẹgbẹ APC yoo ṣe figbanu kan ṣoṣo ṣọja lasiko eto idibo abẹle to n bọ. Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ yoo lo anfaani ipade ọhun lati wa ojuutu si lọgbọ lọgbọ to n ja ranyin ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ, eyi to mu kawọn kan bẹrẹ si i ṣe konko-jabele, kaluku lo n ṣe tiẹ, tawọn mi-in si ti ya kuro ninu ẹgbẹ, wọn lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Lẹyin ipade yii, ireti wa pe Ọjọgbọn Ọṣinbajo yoo tun tẹsiwaju ninu ifikunlukun rẹ kaakiri origun mẹrẹẹrin Naijiria, ki ifa le fọre lasiko pamari naa.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja lọhun-un ni Ọṣinbajo kede erongba rẹ lati jade dupo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023 to n bọ lọna yii.