Ibo abẹle APC: O ṣee ṣe ki ofin idibo ti Buhari ko fọwọ si ṣakoba fawọn aṣoju lati ipinlẹ Eko atawọn mi-in

Jọkẹ Amọri
O to ọjọ mẹta ti awọn ọmọ orileede yii ti n reti ki Aarẹ ilẹ wa, Ọgagun Muhammadu Buhari, fọwọ si atunṣe ofin idibo, eyi ti yoo fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ti o n ba ijọba rẹ ṣiṣẹ atawọn oloye ẹgbẹ mi-in lanfaani lati kopa lasiko idibo abẹle lati yan aarẹ atawọn ipo oṣelu mi-in.
Ṣugbọn titi ta a fi n kọ iroyin yii, Buhari ko ti i fọwọ si atunṣe ofin ọhun tawọn ileegbimọ aṣofin agba fọwọ si, ti wọn si ti fi ranṣẹ si i lati buwọ lu u. Pẹlu bi Aarẹ ṣe kọ lati buwọ lu ofin yii, a jẹ pe awọn aṣoju kan ti wọn n pe ni (Statutory delegates) ko ni i ni anfaani lati kopa ninu eto idibo abẹle ti yoo waye ninu awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri ilẹ wa.
Awọn aṣoju tọrọ naa kan ni awọn to jẹ nipa ipo oṣelu ni wọn fi yan wọn sipo bii minisita, awọn oludamọran ati gbogbo awọn to di ipo oṣelu kan tabi omi-in mu ninu ijọba Buhari. Bakan naa lofin yii mu awọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ APC, igbimọ amuṣẹṣe, awọn gomina ati igbakeji wọn to wa nipo ati eyi to ti ṣejọba tan. O kan aarẹ ati igbakeji rẹ, ọmọ ileegbimọ aṣofin to wa nibẹ atawọn ti wọn ti ṣe sẹyin, awọn oloye ẹgbẹ oṣelu lati ipinlẹ kọọkan, awọn alaga ijọba ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ohun to tumọ si ni pe aṣoju mẹta mẹta lati ijọba ibilẹ to din diẹ ni ni ẹgbẹrin (774) to wa lorileede yii nikan lo lanfaani lati kopa ninu eto idibo abẹle ọhun.
Ni eto ti wọn maa n tẹle tẹlẹ, gbogbo awọn eeyan wọnyi ni wọn maa n yan gẹgẹ bii aṣoju wa si ibi idibo abẹle yii, tawọn naa si ni anfaani lati dibo.
Ṣugbọn nitori atunṣe ti wọn ṣe si ofin naa, ti aṣiṣe kekere si wa lati fi orukọ awọn eeyan naa si i, eyi ti awọn aṣofin pada gbe lọ sọdọ Buhari, ti ọkunrin naa si kọ ti ko fọwọ si i titi di ba a ṣe n sọ yii, awọn eeyan naa ko ni i lanfaani lati dibo.
Itumọ eyi ni pe dipo eeyan bii ẹgbẹrun lọna meje ati ẹgbẹrin (7, 800), to yẹ ko kopa ninu eto idibo abẹle naa, ko ni i ni anfaani lati ṣe bẹẹ. Awọn aṣoju mẹta mẹta lati ijọba ibilẹ ni ipinlẹ kọọkan nikan ni wọn ni anfaani lati kopa ninu eto idibo abẹle naa, eyi ti apapọ wọn pẹlu ti olu ilu ilẹ wa niluu Abuja jẹ ẹgbẹrun meji le ni ọọdunrun ati ogoji(2304).
Pẹlu igbesẹ tuntun yii, bi ijọba ibilẹ ba ṣe pọ to ni ipinlẹ kọọkan ni wọn yoo ṣe ni aṣoju ti yoo waa kopa ninu eto idibo abẹle yii. Ko si ki adinku yii ma ṣe akoba fun ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ mi-in ti wọn ti ni awọn oloye ẹgbẹ to pọ ti iba kopa ninu eto naa.
Nitori pe ijọba ibilẹ Ogun pere ni ijọba apapọ ka fun ipinle Eko, bo tilẹ jẹ pe wọn ni ijọba ibilẹ Onidagbasoke si i, awọn awọn aṣoju bii ọgọta pere ni yoo ni anfaani lati dibo lati ipinle Eko. Dipo eeyan bii ọọdunrun ati mẹrin ti iba wa lati ipinlẹ Eko nikan, nitori bi wọn ṣe ni awọn oloye ẹgbẹ to pọ, ọgọta pere ni yoo dibo lati ipinlẹ Eko.
Bakan naa lọrọ yii kan ipinlẹ Borno, ipinlẹ yii wa lara awọn ti wọn ni oloye ẹgbẹ APC ti wọn ti ṣejọba sẹyin atawọn tuntun, eyi ti iba fun wọn ni anfaani lati ni aṣoju to pọ. Ṣugbọn ni bayii, awọn aṣoju mẹta mẹta lati ijọba ibilẹ mẹtadinlọgbọn ti wọn ni nikan ni yoo dibo.
Aifọwọ si ofin tuntun yii yoo si fun awọn ipinlẹ to jẹ pe ẹgbẹ alatako lo n dari nibẹ, ti awọn oloye tabi ọmọ ẹgbẹ ko pọ nibẹ, ṣugbọn ti wọn ni ijọba ibilẹ to pọ. Iru awọn ipinlẹ bẹẹ yoo tun ni aṣoju to pọ ju ipinlẹ Eko, Borno atawọn yooku tọrọ kan.
Awọn ipinlẹ ti anfaani yii yoo tọ si ni Ọyọ, eyi to ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn. Aṣoju mọkandinlọgọrun-un (99) ni yoo wa lati ipinlẹ Ọyọ nikan latari ayipada yii, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ PDP lo n ṣakoso wọn. Bakan naa ni ipinlẹ Akwa Ibom, aṣoju mẹtalelaaadọrun-un (93) ni yoo wa lati ipinlẹ naa nitori iye ijọba ibilẹ ti wọn ni.
Ọṣun yoo ni aadọrun-un (90), nitori ijọba ibile ọgbọn ni wọn ni.
Ohun ti awọn to mọ bọrọ oṣelu ṣe n lọ n sọ ni pe afaimọ ki kinni naa ma ṣakoba fun Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, nitori adinku yoo ba iye awọn aṣoju lati ipinlẹ Eko to ti yẹ ki ibo rẹ rugọgọ si i.

Leave a Reply