Ibo abẹle APC:Awọn gomina, igbimọ apaṣẹ ni iha Guusu loludije sipo aarẹ yoo ti wa

Orẹoluwa Adedeji
Apapọ awọn gomina ilẹ Hausa ti fẹnu ko pe ki awọn eeyan ma mikan, wọn ni iha Guusu naa ni oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC yoo ti wa gẹgẹ bi awọn ṣe fẹnu ko ni Satide, ọsẹ to kọja. Bakan naa ni igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa (NWC), ti kin ọrọ yii lẹyin, wọn ni bi yoo ṣe ri niyẹn.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina Oke-Ọya, to tun jẹ Gomina ipinlẹ Pleateau, Simon Lalong, lo sọrọ naa fawọn oniroyin lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Buhari lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
O sọ lorukọ awọn gomina mẹtala yooku pe ipinnu awọn, ninu eyi ti awọn ti kọwọ bọwe pe ipo aarẹ yoo lọ si apa Guusu ilẹ wa ṣi wa bẹẹ. O ni igbesẹ yii waye lati le gba alaafia ati iṣọkan laaye. Ati pe awọn ṣi waa ni ifikunlukun pẹlu Buhari ni ipade tọjọ Aje yii fi waye.
O fi kun un pe Buhari ko fa oludije kankan kalẹ tabi pe o n ṣatilẹyin fun eyikeyii ninu awọn oludije mẹtalelogun naa. O ni aṣẹ ti Buhari kan pa ni pe ki awọn gomina ri igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa, iyẹn (National Working Committee) lati ṣepade, ki wọn le foun ṣọkan lori ẹni kan ninu awọn oludije naa lọna to ba dẹmokiresi mu

Leave a Reply