Ibo abẹle Ondo: Kekemeke loun ko ni igbẹkẹle ninu ẹ, Abraham naa binu kuro

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọkan ninu awọn to n dije sipo gomina ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, ti pariwo pe oun ko ni igbẹkẹle kankan ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo tẹlẹ ri ọhun ni lati igba tawọn asaaju ẹgbẹ ti ta ku lori ilana ti wọn fẹẹ ṣamulo ninu eto idibo abẹle naa loun ti mọ pe ejo wọn ti n lọwọ ninu.

Bakan naa ni Kekemeke tun fẹsun kan gomina ipinlẹ Kogi, Alaaji Yahaya Bello, to jẹ alaga igbimọ to n ṣeto idibo ọhun pe ko ka awọn oludije yooku si rara, yatọ si Akeredolu nikan. O ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Aiku, Sannde, nigba ti eto idibo naa ku bii wakati perete ko bẹrẹ loun sẹsẹ n ri iwe akọsilẹ orukọ awọn aṣoju to fẹẹ dibo, eyi to lodi si ilana ti wọn fi n ṣeto ibo abẹle.

Ọkan ninu awọn olukopa mi-in, Oluṣẹgun Abraham, loun ko ni i kopa ninu eto abẹle naa mọ. Ọkunrin naa ni oun ko nigbagbọ ninu awọn ti wọn n ṣe kokaari eto naa.

Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kunle Adumashi, lo fidi eleyii mulẹ.

Leave a Reply