Ibo abẹle PDP: Atiku fẹyin Wike, Saraki ati Udom janlẹ

Adewumi Adegoke
Igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Alaaji Abubakar Atiku, lo tun wọle ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP lati dupo aarẹ ọdun to n bọ lorukọ ẹgbẹ naa.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni eto idibo naa waye ni papa iṣere MKO Abiọla, to wa niluu Abuja. Ibo ọtalelọọọdunrun ati ẹyọ kan (371) lo ni, nigba ti Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ni ibo ojilenigba o din mẹta (237). Ibo aadọrin (70), pere ni gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki ni ni tirẹ. Udom Emmanuel to jẹ gomina ipinlẹ Akwa Ibom ni ibo mejidinlogoji.
Pẹlu esi idibo wọn yii, oun ni yoo koju ẹnikẹni ti ẹgbẹ APC ba fa kalẹ ninu idibo ọdun to n bọ.
Lati ọdun 1993 to ti bẹrẹ oṣelu, Atiku Abubakar ti dije dupo aarẹ fun igba marun-un, ti ko si yege, eyi to ṣeṣẹ fẹẹ lọ yii ni yoo jẹ igba kẹfa ti yoo dije.
Latigba ti esi idibo abẹle naa ti jade lawọn ololufẹ rẹ ti n ki i ku oriire.

Leave a Reply