Ibo Abẹle PDP: Awọn tọọgi lu ọlọpaa, oniroyin atawọn alatako Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọpọlọpọ ọlọpaa ati oniroyin lo fara pa nibi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), to waye ni papa iṣere Lekan Salami, laduugbo Adamasingba, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Awọn ọlọpaa lo na oniroyin, iyẹn, Yinka Adeniran, to jẹ akọroyin fun The Nation, nigba ti iya buruku to jẹ awọn agbofinro waye latọwọ awọn tọọgi to wa nibi eto idibo naa.
Ki i ṣe iroyin mọ pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo wọle idibo naa pẹlu ojilelẹgbẹrun (1040) ibo, nigba ti Amofin Azeem Gbọlarumi to jẹ alatako rẹ ni ẹyọ ibo meji (2) pere.
Fọpomọyọ ọhun bẹrẹ nigba ti awọn adari eto naa bẹrẹ si i ṣafihan awọn mejeeji to n jijadu lati gba tikẹẹti gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo gomina lorukọ ẹgbẹ PDP. Orukọ Makinde ni wọn kọkọ pe, gbogbo awọn alatilẹyin rẹ si n sa a ni mẹsan-an mẹwaa. Ṣugbọn nigba ti awọn ololufẹ Gbọlarumi pariwo lati ṣafihan atilẹyin wọn fun oludije naa, nṣe lawọn tọọgi ya bo wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ko igbaju, igbamu ati ikuuku bo wọn.
Ọga awọn onimọto kan n’Ibadan lo ko awọn tọọgi naa sodi lọọ ba awọn alatilẹyin oludije naa nibi ti wọn jokoo si, bo ṣe paṣẹ pe ki wọn lu awọn eeyan naa ni wọn bo wọn bii igba ti eera ba bo ṣuga.

Wọn ko yọ awọn obinrin inu wọn silẹ, atọmọde atagba ni wọn fi igbaju olooyi le dide nibi ti wọn jokoo si, wọn si ṣe bẹẹ lu wọn titi ti awọn ẹniẹlẹni fi fi ibudo idibo naa silẹ.
Ibinu iṣẹlẹ yii lo mu ki Gbọlarumi fi ẹdun ọkan ẹ han nigba ti wọn pe e lati waa ba awọn oludibo sọrọ, o ni awọn oludibo wo loun tun fẹẹ ba sọrọ, nigba ti awọn tọọgi ti le awọn alatilẹyin oun lọ tan.
Ko pẹ sigba naa lawọn tọọgi ya lu ọlọpaa kan, wọn lu u lalugba to bẹẹ to jẹ pe gbogbo didi to di papaapa gẹgẹ bii onikaki ni wọn tu, bẹẹ ni wọn ja bọtinni aṣọ ẹ. Ọlọpaa ẹgbẹ ẹ to fẹẹ gbija ẹ, wọn lu oun naa bii ẹni lu bẹnbẹ. Ọlọpaa to si fara pa nibi iṣẹlẹ yii ki i ṣe kekere.
Ọgbẹni Adeniran, ẹni to jade lọ fun iṣẹ pataki kan nigboro Ibadan, lawọn ọlọpaa ko gba fun lati wọle.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, kaadi idanimọ to fi han awọn ọlọpaa gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oniroyin ọfiisi gomina lo bi wọn ninu ti wọn ko fi gba a laaye lati wọle, wọn gba pe alatilẹyin Gomina Makinde lo na awọn ọlọpaa, wọn si ri oun naa gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹni ti ko fẹran awọn.
Ọkan ninu awọn agbofinro wọnyi yin tajutaju (tiagaasi) si oniroyin naa loju, o fa aṣọ ya mọ ọn lọrun, ọ si fiya jẹ ẹ bii ẹni maa pa a ki awọn oniroyin ẹgbẹ ẹ too sare ṣugbaa ẹ lati gba a silẹ lọwọ iya ajẹpalori.
Alaga ẹgbẹ awọn oniroyin, Ọgbẹni Ademọla Babalọla, ti waa rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣewadii iṣẹlẹ yii, ki wọn si fiya to ba tọ jẹ ọlọpaa to huwa ika naa.

Leave a Reply