Ibo Ekiti: Ẹ jẹ ka gbagbe gbogbo ija to ti ṣẹlẹ, ki ẹgbẹ wa le rọwọ mu ni Satide- Tinubu

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
‘‘Ko ni i jẹ ami to dara fun ẹgbẹ wa, paapaa bi eto idibo ipo aarẹ ṣe n sun mọ etile ka padanu idibo ti yoo waye lọjọ Satide, nipinlẹ Ekiti. Idi niyi ti gbogbo awọn to n binu ninu ẹgbẹ naa fi gbọdọ ko ara wọn papọ, ki wọn fimọ ṣọkan, ki wọn si ri i pe ẹgbẹ APC rọwọ mu lasiko idibo gomina ti yoo waye lopin ọsẹ yii ni ipinlẹ naa’’.
Oludije ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lo sọ eyi di mimọ lasiko to lọ siluu Ekiti lati kopa ninu aṣekagba ipolongo ibo ti wọn ṣe fun ondije lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa Biọdun Oyebanji, eyi to waye ni gbọngan Ekiti Parapọ, niluu Ado-Ekiti.
Tinubu, ẹni ti awọn gomina APC bii mẹrinla kọwọọrin pẹlu rẹ rọ awọn eeyan ilu pe ki wọn ma ja oun kulẹ, ki wọn dibo fun ẹgbẹ awọn, nitori bi ibo yii ba ṣe ri ni yoo sọ bi ibo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ yoo ṣe ri.
O ni latọdun 2015 ni ẹgbẹ APC ti di alagbara nla to n gba awọn PDP danu sigbo. O ni ipilẹ agbara ti awọn fi gba PDP danu yii bẹrẹ lati ọdun 2015, lati ọdọ Buhari, o waa rọ wọn ki wọn jẹ ki o tẹsiwaju nipa didibo fun un lọdun to n bọ lati wọle sipo aarẹ Naijiria.
Lara awọn gomina to kọwọọrin pẹlu rẹ ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Ondo, Ogun, Eko. Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Kaduna, Gombe, Nassarawa, Jigawa, Plateau, Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Adamu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii ni eto idibo sipo gomina nipinlẹ Ekiti yoo waye.

Leave a Reply